Ọwọ ọlọpaa tẹ awọn ọdọ mejila, ile ati ṣọọbu ni wọn lọọ fọ l’Ado-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ awọn ọdọ langba ti ko din ni mejila lẹyin ti wọn lọọ fọ ile ati ṣọọbu ni Ado-Ekiti, olu ilu ipinlẹ Ekiti.

Orukọ awọn ọdaran naa ni: Akinyẹmi Ojo, Akanle Ọlaniyi, Adebayọ Jamiu, Nwafor Ifeanyi, Adewumi Ademọla, Abdullahi Musa, Sunday Tọmiwa, Yaya Yinusa, Fẹmi Dipọ ati awọn miiran ti wọn ko pe orukọ wọn.

Awọn ọlọpaa ayaraṣaṣa, Rapid Respond Squad (RRS), lo mu awọn eeyan naa lẹyin ti awọn araalu ta wọn lolobo. Lẹyin ti wọn mu wọn ni wọn ti wọn mọ ileeṣẹ ẹka RRS to wa loju ọna to lọ lati Ado-Ekiti si ilu Iyin-Ekiti.

Awọn ọdaran naa ti ọjọ ori wọn ko ju bii ọgbọn ọdun lọ lọwọ tẹ ni ibuba wọn to wa ni adugbo Ajilosun, Idẹma, Ajebandele, Dalemọ ati Adebayọ lẹyin ti wọn lọọ fọ ile ati ṣọọbu tan.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, ṣalaye pe ọwọ tẹ awọn ọdaran naa pẹlu ifọwọsọwọpọ awọn araalu ati awọn eeyan ti awọn ọdaran naa fọ ile wọn.

Diẹ lara awọn ẹru ti wọn gba lọwọ awọn janduku wọnyi nii foomu ibusun nla kan, bẹẹdi onigi nla kan, ẹrọ amuletutu kan, firiiji nla kan, ẹrọ amunawa meji, ẹya jẹnẹretọ lọpọlọpọ, bata mẹwaa, aṣọ obinrin ati ti ọkunrin lọpọlọpọ.

O fi kun un pe gbogbo awọn ọdaran naa ni wọn ti jẹwọ pe loootọ lawọn ṣẹ ẹṣẹ naa, o ni gbogbo wọn ni wọn yoo ko lọ sile-ẹjọ ni kete ti wọn ba ti pari iwadii lori ọrọ naa.

Leave a Reply