Ọwọ ọlọpaa tẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn ji oyinbo gbe l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ọwọ palaba awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn fọ banki Igbalode kan ni Iyin-Ekiti t segi, pẹlu bi ọwọ ajọ Ọlọpa ipinlẹ naa ṣe tẹ wọn.

Gẹgẹ bii alukoro ajọ ọlọpa ipinlẹ Ekiti Ọgbẹni Sunday Abutu, ṣe sọ, oni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti ọwọ wọn ko din ni mẹsan, ni ile itura kan l’Ado-Ekiti, ni wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ, ti wọn si ti dingun ja oriṣiiriṣii ile itura ati ibi igbafẹ ni ipinlẹ naa.
O ṣalaye pe lọjọ ti ọwọ palaba wọn segi yii, ile iwosan kan to jẹ ti aladaani to wa ni adugbo Rova, ni Ado-Ekiti, ni wọn lọ, ti wọn si fibọn gba gbogbo owo awọn eeyan, to fi mọ awọn alaisan to wa nileewosan naa.
O fi kun un pe awọn okunrin meji ti orukọ wọn n jẹ Ojo Emmanuel, Balogun Ahmed ti wọn gbe alaisan wa si ọsibitu naa ni wọn fi ibọn gba gbogbo owo ọwọ wọn, bakan naa ni wọn tun gba oun ẹṣọ bii oruka igbeyawo, ẹrọ kọmputa ati ẹrọ ilewọ.
Abutu ṣalaye pe bi awọn adigunjale naa ṣe n jade kuro ninu ileewosan naa ni wọn ja ọkọ ayọkẹlẹ kan to jẹ ti Ọgbẹni Ojo Dada gba, ti wọn si kọri sibi ti ẹnikẹni ko mọ.
Awọn ọdaran naa gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa ṣe sọ ni Lasisi Afeez, Ọmọtoyinbo Samuel, Ajewọle Peter ati Ilesanmi Ṣeun. Bakan naa ni wọn tu mu ọkunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan, Ojo Busayọ to ko ibọn ilewọ alagbelẹrọ ati ọta inu rẹ fun awọn ọdaran naa.

Nigba ti awọn ọlọpaa n fọrọ wa wọn lẹnu wo, wọn jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ ni awọn, awọn si ti bẹrẹ iṣẹ idigunjale lati ọdun 2015.
Aimọye ileewosan to jẹ ti aladaani ni wọn ni awọn ti digun ja lole nipinlẹ Ekiti. Bakan naa ni wọn tun fọ ile ifowopamọ igbalode kan ni Iyin-Ekiti. Wọn tun jẹwọ pe awọn lawọn ji oyinbo alawọ funfun kan gbe nibi ti wọn ti n n ṣiṣẹ ọna ni Ado-Ekiti.
Lara awọn ẹgbẹ wọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ ti wọn tun darukọ ni: Fadairo Oyindamola, Akinlẹyẹ Ṣeyi, Samuel Ọmọiku, Yeye Orio ati Tunji Tunde ti ọwọ awọn ọlọpaa ti kọkọ tẹ lọdun to kọja, ti wọn si ti wa lọgba ẹwọn lọwọlọwọ lori ẹsun idigunjale.
Awọn ọmọ ẹgbẹ wọn mi-in ti wọn ni ilu Abuja ati ipinlẹ Ondo lawọn n gbe ni: Afẹ Ayodeji, Adejumọ Kẹhinde, Ardnoi Samuel.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: