Ọwọ ọlọpaa tẹ awọn to fẹhonu han fun titapa sofin Korona n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

 

Awọn mẹfa laarin awọn olufẹhonu han to kora jọ laarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, siwaju ile ijọba niluu Ilọrin, lọwọ ọlọpaa tẹ fẹsun titapa si ofin Covid-19 to ta ko kikorajọ ati fun dida alaafia ilu ru.

Awọn tọwọ tẹ ni; Aransiọla Olubukun, Salaudeen Abubakar, Mohammed Sọliu, Ibahim Alabi, Isiaka Toyin ati Adewale Abdulazeez.

Labẹ asia awọn olukọ tijọba ana gba siṣẹ, ṣugbọn tijọba to wa lori ipo loni le danu, eyi ti wọn n pe ni (Sunset Teachers), lawọn olufẹhonu han naa to jokoo soju ọna Ahmadu Bello, ti wọn si di irinna ọkọ loju ọna naa lọwọ.

Ohun tijọba to wa nipo bayii sọ ni pe ilana tijọba ana fi gba wọn sẹnu iṣẹ lodi sofin, ati pe ọpọlọpọ lara wọn ni ko ni iwe-ẹri iṣẹ olukọ ti wọn gba wọn si, fun idi eyi, ki wọn gba ile wọn lọ.

Lati bii ọsẹ meloo kan sẹyin lawọn eeyan ọhun ti n fapa janu, wọn fẹdun ọkan wọn sijọba lori bo ṣe gbaṣẹ lọwọ wọn.

Bo tilẹ jẹ pe awọn agbofinro, paapaa ọlọpaa, ko da wọn lọwọ kọ latigba ti wọn ti n fẹhonu han wọọrọwọ, ṣugbọn igbesẹ ti wọn gbe l’Ojọruu lati ṣediwọ fawọn araalu to n ṣiṣẹ oojọ wọn lọna ti wọn ti pa naa lo mu kawọn ọlọpaa lọọ ko lara wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ajayi Ọkasanmi, ni ẹtọ gbogbo ọmọ orilẹ-ede yii ni lati fẹhonu han alalaafia, ṣugbọn iru ifẹhonu han bẹẹ ko gbọdọ jẹ idiwọ fun araalu tabi ṣakoba fun alaafia ilu.

O ni Ọga ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Mohammed Lawal Bagega, fi da araalu loju pe aabo to peye wa fun dukia ati ẹmi wọn. O ṣekilọ fawọn to ba fẹẹ tẹ ofin loju lati jawọ kia bi bẹẹ kọ, wọn yoo kan idin ninu iyọ.

 

Leave a Reply