Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokutan
Niṣe lo jọ pe awọn ajinigbe atawọn ọlọpaa ti jọ pinnu pe awọn yoo ba ara awọn mu nnkan nilẹ nipinlẹ Ogun lasiko yii, pẹlu bi wọn ṣe n dọde ara wọn, ti ọwọ ọlọpaa si n ba awọn amookunṣika naa.
Inu igbo kan ti wọn n pe ni Ilala, niluu Imala, nijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta, ni ọwọ ọlọpaa ti tẹ ajinigbe kan to pe ara ẹ ni Usman Maidama, bẹẹ ni wọn yinbọn pa ajinigbe mi-in ninu awọn mẹfa ti wọn wa ninu igbo naa lọjọ Aje, Mọnde, ọgbọnjọ, oṣu kẹjọ, 2021.
Awọn kan ni wọn ta awọn ọlọpaa Imala lolobo, pe awọn ri awọn mẹfa kan ti wọn dihamọra ogun ninu igbo Ilala. Eyi lawọn ọlọpaa ṣe kora jọ pẹlu awọn ikọ alaabo mi-in, ti wọn wọnu igbo naa lọ.
Bi wọn ṣe debẹ lawọn ti wọn n wa ti ri wọn lọọọkan, ọwọ kan naa ni wọn ṣina ibọn bolẹ fawọn ọlọpaa, tawọn iyẹn naa si n da a pada fun wọn gẹgẹ bo ṣe maa n ri.
Alukoro ọlọpaa Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣalaye pe nibi ija naa ni awọn ọlọpaa ti pa ajinigbe kan, ti wọn mu ikeji laaye, ti awọn yooku wọn si sa lọ pẹlu ọta ibọn lara wọn.
Oyeyẹmi sọ pe laarin ọsẹ mẹta pere, ibọn AK 47 mẹrin lawọn ti ri gba lọwọ awọn ajinigbe, awọn mi-in si ti ṣagbako iku ninu wọn.
Ibọn kan ni wọn ri gba lọwọ Usman, ajinigbe tọwọ ba yii, wọn tun ri nnkan ibomu to n lo naa ati bata olokun kan.
Ẹka to n ri si ijinigbe ni wọn mu eyi tọwọ ba yii lọ, bẹẹ ni wọn ṣi n wa awọn yooku rẹ to sa lọ.
Ẹ oo ranti pe lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lawọn ajinigbe meji kan naa ku l’Ewekoro, nigba ti wọn wọya ija pẹlu awọn ọlọpaa lagbegbe Itori.