Ọwọ ọlọpaa tẹ Kẹhinde pẹlu ori ati ọwọ eeyan l’Ajaṣẹ-Ipo, o loun fẹẹ fi ṣoogun owo ni

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Ọdọmọkunrin kan, Kẹhinde John Moses, ti ha sọwọ awọn ọlọpaa nipinlẹ Kwara, nitori bi wọn ṣe ba agbari ati ọwọ eeyan tutu lọwọ ẹ to fẹẹ fi ṣoogun owo.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Ajayi Ọkasanmi, ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹfa aabọ aarọ ọjọ kẹta, oṣu karun-un, ọdun yii, lọwọ awọn agbofinro to n ṣe ayẹwo loju popo tẹ afurasi naa lọna Ajaṣẹ-Ipo si Ilọrin.

Ọkasanmi sọ pe nigba ti wọn da ọkọ bọọsi akero kan ti Kẹhinde ati ọrẹ kan wọ duro, bi wọn ṣe fẹẹ yẹ apo kan ti wọn gbe lọwọ wo ni ẹni keji sa lọ.

O ni si iyalẹnu awọn ọlọpaa to da wọn duro, bi wọn ṣe wonu apo naa, agbari tutu ati ọwọ meji ni wọn ba ninu ẹ.

O tẹsiwaju pe lasiko iwadii lawọn afurasi naa jẹwọ pe Mohammed lorukọ ẹni tawọn pa naa n jẹ, oun pẹlu ọrẹ oun to sa lọ naa lawọn jọ pa a niluu Ajaṣẹ-Ipo, oogun owo lawọn fẹẹ fi i ṣe.

Ọkasanmi ni afurasi naa mu awọn ọlọpaa de ibi ti wọn pa Mohammed si, wọn ti gbe iyooku ara rẹ gbe lọ silewosan fun ayẹwo.

Ẹwẹ, Ọga ọlọpaa, Mohammed Lawal Bagega, ti paṣẹ fun iwadii to peye, ki wọn si mu gbogbo awọn to ba mọ nipa ẹ.

Leave a Reply