Ọwọ ọlọpaa tẹ mẹrinla ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to n yọ wọn lẹnu n’Ikorodu

Faith Adebọla, Eko

Mẹrinla lara awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun ‘Aiye’ to n da wahala silẹ lagbegbe Ikorodu, nipinlẹ Eko, ti ha sọwọ ọlọpaa bayii. Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni wọn ko wọn, obinrin meji si wa lara wọn.

Orukọ awọn afurasi tọwọ ba naa ni Kazeem Akinpẹlu, Tobi Awoyẹfa, Ṣegun Ariyọ, ti inagijẹ rẹ n jẹ Zangalo, Hassan Ashiru, Ibrahim Oni, Micheal Ọnafọwọkan, Damọla Oyesanya, Yusuf Okunlọwọ, Tọheeb Adeṣina, Bọla Hassan ati Julius Ihara.

Damilọla Adeọla ati Adeọla Fọlahan lawọn meji to jẹ obinrin ninu wọn.

Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Olumuyiwa Adejọbi, sọ ninu atẹjade kan to fi sọwọ s’ALAROYE nipa iṣẹlẹ ọhun pe ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu yii, lawọn ọlọpaa gba ipe pajawiri lati adugbo Agunfoye, n’Ikorodu.

Nigba ti ikọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ fi maa debẹ, ọdọmọkunrin, Taiwo Lasisi, ẹni ogun ọdun, lọwọ ba, adugbo naa lo n gbe, wọn si ba ibọn ilewọ oyinbo kan lọwọ ẹ. Oun lo ṣatọna tọwọ awọn agbofinro fi ba awọn mẹtala to ku. Awọn tọwọ ba yii jẹwọ pe ẹgbẹ okunkun ‘Aiye’ lawọn.

Awọn nnkan ti wọn ka mọ wọn lọwọ ni foonu olowo nla i-phone mẹjọ, foonu Tecno meji, foonu Nokia kan, apamọwọ mẹta ti wọn ko goolu ati owo si, bẹliiti dudu kan, ankaṣiifu funfun kan ti wọn di iṣana oyinbo (laita) mẹrin sinu rẹ, Lailọọnu baagi dudu kan ti wọn ko oriṣiiriṣii oogun abẹnu gọngọ si, ọta ibọn ti wọn ti yin ati eyi ti wọn ko ti i yin, kẹẹgi oni-lita mẹẹẹdọgbọn ti wọn rọ kẹmika egboogi oloro ti wọn n pe ni skuchies si.

Ni ti Ṣẹgun ti wọn mọ si Zangalo, Adejọbi ni awọn ọlọpaa SARS ti figba kan mu ọmọkunrin yii, ko too pada sa lọ.

Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa, Hakeem, ti paṣẹ pe ki wọn ko awọn afurasi naa lọ si Panti, ni Yaba, ibẹ lawọn ọtẹlẹmuyẹ yoo ti wadii daadaa nipa wọn, ki wọn too ṣeto ati foju wọn ba ile-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply