Ọwọ ọlọpaa tẹ oṣiṣẹ banki atawọn meji mi-in ti wọn digunjale l’Ọṣun

Florence Babaṣọla

Ileefowopamọ kan niluu Eko ni Keffi Moses, ẹni ọdun mejidinlogoji, ti n ṣiṣẹ tẹlẹ, asiko wahala Korona la gbọ pe wọn da a duro lọdun to kọja, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti ṣafihan rẹ bayii lori ẹsun ole jija.

Yatọ si Keffi, awọn afurasi meji mi-in ti ọwọ tun tẹ ni Ọdẹyẹmi Oluwafẹmi, ẹni ọdun mejilelogoji, ati Isah Lawal toun jẹ ẹni ọdun mejidinlọgbọn.

Nigba to n ṣafihan wọn, Kọmiṣanna funleeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Wale Ọlọkọde, ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹrin idaji ọjọ kẹrinla, oṣu kin-in-ni, ọdun yii ni ọwọ tẹ awọn afurasi mẹtẹẹta yii loju ọna Osu si Ileefẹ.

O ni tibọntibọn ni wọn ja ọkọ tirọọki meji gba lọjọ naa. Wọn gba Iveco Truck kan to ni nọmba DTM 19 AX ti awọn nnkan eelo inu ile ti owo rẹ jẹ ọkẹ aimọye miliọnu gba.

Bakan naa ni wọn gba DAF 75 Truck to ni nọmba JJI 445 XT ti wọn ko ofifo apo koko si. Wọn gba owo to to ẹgbẹrun lọna aadoje naira (#130,000) ati foonu lọwọ awọn ti wọn ba ninu tirọọki mejeeji.

Ọlọkọde sọ siwaju pe ni kete ti wọn fi iṣẹlẹ naa to awọn ẹṣọ ITF ati ti ọlọpaa ti wọn wa lagbegbe yẹn leti niṣẹ ti bẹrẹ, ti ọwọ si tẹ awọn afurasi mẹtẹẹta pẹlu bọọsi funfun kan to ni nọmba LSR 214 YC ti wọn fi maa n ṣiṣẹ pẹlu foonu ti wọn ti ji.

O ni tiwadii ba ti pari lawọn mẹtẹẹta yoo foju bale ẹjọ. Bẹẹ lo tun kilọ pe ko si ọdaran ti yoo faraare lọ nipinlẹ Ọṣun.

Leave a Reply