Ọwọ ọlọpaa tẹ Sikiru pẹlu ẹya ara eeyan n’Ikorodu, o loun feẹ fi ṣoogun owo ni

Jọkẹ Amọri

Ilu Ikorodu ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko ti mu ọmọkunrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Sikiru Kọlawọle pẹlu ọkan eeyan ọwọ meji ati ẹran ara to loun fẹẹ fi ṣoogun owo.

Ọmọkunrin yii ṣalaye fawọn ọlọpaa pe iṣẹ oun ni ko lọ deede, toun si ṣalaye fun ọrẹ oun kan. Ọrẹ oun yii lo mu oun lọ sọdọ aafaa kan, ti aafa yii si ni koun lọọ wa ẹya ara eeyan wa ti oun yoo fi ṣe aajo foun ti oun yoo fi di olowo.

O ni eyi lo mu ki oun ṣe iwadii ibi ti oun ti le ri ohun ti aafaa beere yii, awọn kan ni wọn si juwe fun oun pe oun le ri ni itẹkuu.

Ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogoji yii sọ pe eyi lo gbe oun lọ si itẹkuu kan to wa ni Sabo, loju ọna Igbogbo, n’Ikorodu, niluu Eko, nibi ti oun ti ri saare ti wọn ṣẹṣẹ sin oku si, ti oun si hu u. Loun ba yọ ọkan oku naa, oun si ge ọwọ rẹ mejeeji ati ẹran ara rẹ gẹgẹ bi aafaa naa ṣe ni ki oun mu un wa.

Nigba to n ṣalaye bi ọwọ ṣe tẹ ẹ, o ni nigba ti oun n kọja lọ ni awọn ọlọpaa da oun duro, ti wọn si beere pe ki oun saa wo ohun to wa ninu apo ti oun gbe lọwọ. Lasiko naa ni aṣiri tu pe ẹya ara eeyan loun gbe, bi wọn ṣe mu oun ṣinkun niyẹn.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ni lootọ ni ọwọ tẹ ọmọkunrin naa pẹlu ẹya ara eeyan ati ọbẹ to fi ge e nitẹkuu. O fi kun un pe lẹyin tawọn ba ti pari gbogbo iwadii to yẹ ni yoo foju bale-ẹjọ

 

Leave a Reply