Ọwọ ọlọpaa ti tẹ marun-un ninu awọn to n ja ọkada gba n’Ijoko

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ikọ ẹlẹni mẹjọ kan wa n’Ijoko, nipinlẹ Ogun, to jẹ jija ọkada gba lọwọ awọn to n wa a ni iṣẹ tiwọn. Marun-un ninu wọn lọwọ ba lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2020.

 Awọn tọwọ ọlọpaa Sango ba naa ni: Yusuf Ogundimu; ẹni ọdun mẹtalelogun (23), Moses Anthony; ẹni ọdun mẹtalelogun, Mọruf Ọlafimihan; ẹni ọdun mẹrinlelogun (24),Tọheeb Ṣhọla; ẹni ọdun mejilelogun (22) ati Adeyẹmi Azeez; ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27)

 Awọn agbegbe bii Ijoko, Ifọ ati Sango ni DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, sọ pe wọn ti maa n ṣọṣẹ, ti wọn maa gba ọkada lọwọ awọn to n fi i ṣiṣẹ oojọ wọn.

 Lọjọ Aje tọwọ ba wọn yii, wọn tun ti mu ẹnikan mọlẹ, nibi ti wọn ti fẹẹ maa gbe ọkada ẹ lọ ni olobo ti ta awọn ọlọpaa ni teṣan Sango, bi wọn ṣe kan awọn afurasi ole naa lara niyẹn.

 Wọn gbiyanju lati sa, awọn mẹta si rọna sa lọ ninu wọn. Ibọn kan, ọta ibọn mẹwaa ti wọn ko ti i yin ati ọkada Bajaj ti nọmba ẹ jẹ  EDO 23 QL lawọn ọlọpaa ri gba lọwọ wọn.

 CP Edward Ajogun ti ni ki wọn wa awọn mẹta to sa lọ naa ri, ki wọn si ko awọn tọwọ ba yii lọ sọdọ awọn SARS, fun itẹsiwaju itọpinpin.

Leave a Reply