Ọwọ ọlọpaa ti tẹ mẹta ninu awọn adigunjale to yinbọn pa Afaa Jamiu l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn afurasi mẹta kan lori Afaa kan ti wọn yinbọn pa laduugbo Yaba, niluu Ondo, laarin ọsẹ to kọja.

Nnkan bii aago mẹjọ aarọ ọjọ Isẹgun,Tusidee, ọsẹ to kọja, ni wọn lawọn adigunjale mẹta kan gun ọkada wa si agbegbe ọhun pẹlu erongba ati waa ja ọmọbinrin oni POS kan lole.

Owo lọmọbinrin naa kọkọ ro pe wọn waa san nigba ti wọn wọle sinu sọọbu rẹ, ṣugbọn ni kete to ti mọ erongba wọn lo ti sa jade, to si n pariwo ‘ole,ole’ kawọn eeyan le mọ iru alejo to gba.

Kiakia lawọn araadugbo ti sare jade, ti olukuluku wọn si fa igi atawọn nnkan mi-in ti wọn ri yọ lati fi doju ija kọ awọn adigunjale ọhun.

Eyi ni wọn lo ṣokunfa bi ọkan ninu awọn adigunjale naa ṣe fa ibọn yọ, to si yin in lu Aafaa Jamiu Rasheed, ẹni ọdun mejilelọgbọn.

Iṣẹ awọn to n ge gilaasi Alumako la gbọ pe oloogbe naa n ṣe nigba to wa laye, ṣọọbu rẹ si fẹgbẹkẹgbẹ pẹlu ti ọmọbinrin ti wọn fẹẹ waa ja lole yii ni.

Loju ẹsẹ lawọn eeyan tisẹlẹ ọhun ṣoju wọn ti lọọ fọrọ naa to wọn leti ni tesan Yaba, ti wọn si fi da wọn loju pe awọn mọ ọkada ti wọn waa fi ṣiṣẹ ibi naa daadaa ti awọn ba ri i.

Ọlọkada ọhun, Ọlagunju Taiwo, to jẹ ọmọ bibi ilu Ondo lọwọ awọn ọlọpaa kọkọ tẹ lagbegbe Yaba lọjọ keji isẹlẹ naa. Oun lo mu wọn lọ sile ti afurasi keji, Ilusanmi Moses, n gbe laduugbo Ayefẹrere, Okelisa, niluu Ondo.

Moses ati ẹgbọn rẹ obinrin kan to gbiyanju ati gbe e pamọ fawọn ọlọpaa ni wọn jọ fi panpẹ ofin gbe lọjọ naa, ti wọn si ko gbogbo wọn lọ si tesan fun ifọrọwanilẹnuwo.

Olori ikọ awọn adigunjale ọhun, ThankGod Friday, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Emeka ni wọn mu kẹyin. Awọn ẹmẹwa rẹ tọwọ kọkọ tẹ ni wọn ṣeto bi wọn ṣe ri oun naa mu laduugbo Ọlaniyan, Yaba, niluu Ondo.

ALAROYE gbọ lati ẹnu ọlọpaa kan pe ko ti i pẹ rara tawọn afurasi mẹtẹẹta ṣẹṣẹ de lati ọgba ẹwọn ti wọn wa lati bii ọdun diẹ sẹyin lori ẹsun idigunjale.

O ni inu ọgba ẹwọn lawọn mẹtẹeta ti pade, ti ọwọ wọn si wọ ọwọ ninu isẹ adigunjale ti wọn yan laayo. Emeka ni wọn lo pada jẹwọ, to si ni oun gan-an lẹni to yinbọn to ṣeku pa Afaa Jamiu lọjọ naa, wọn lo sọ fawọn ọlọpaa pe aṣiṣe patapata lọrọ ibọn to ba ọkunrin naa jẹ nitori ṣe loun fẹẹ yin in si aarin awọn eeyan lati le wọn sẹyin diẹ ki awọn fi rọna sa lọ.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, fidi isẹlẹ yii mulẹ fun wa lasiko to n ba wa sọrọ lori ago.

O ni loootọ lọwọ ti tẹ awọn afurasi mẹta lori ọrọ iku Afaa Jamiu, iwadii iṣẹlẹ naa si n tẹsiwaju. O fi kun un pe o ṣee ṣe kawọn afurasi naa foju bale-ẹjọ lẹyin ti awọn ọlọpaa ba pari iwadii wọn.

Leave a Reply