Ọwọ ọlọpaa ti tẹ mẹta ninu awọn Fulani to fibọn fọ ẹnu iya oniyaa n’Ijẹbu-Oru

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Kọmandi ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti mu mẹta ninu awọn Fulani to kọ lu iya kan, Morounkeji Salami, lopin ọsẹ to kọja yii, ti wọn yinbọn fun un, ti wọn tun ṣa a ladaa kari ara lagbegbe Ijẹbu-Oru, nipinlẹ Ogun.

Nigba to n sọ bi ọwọ ṣe ba wọn, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣalaye f’ALAROYE pe lẹyin tawọn Fulani naa yinbọn mọ iya yii tan ni wọn sa wọgbo lọ, ti wọn si fi awọn maaluu wọn silẹ. O ni nigba ti olobo ta awọn ọlọpaa agbegbe yii lori ikọlu naa, wọn lọ sibẹ, wọn si fara ṣoko sibi kan lati mọ boya awọn Fulani naa yoo tun yọju lati waa ko awọn maaluu wọn nigba ti ilẹ ba rọ.

Bẹẹ naa lo si ri, awọn Fulani ọhun pada wa lati ko maaluu wọn, nigba naa lọwọ ba mẹta ninu wọn. Alukoro ti ni awọn yoo ri i daju pe ọwọ ba awọn marun-un yooku laipẹ.

Ṣe ṣaaju ni iroyin ti tan kalẹ pẹlu fidio kan to ṣafihan Abilekọ Morunkeji pẹlu bandeeji lori, ati ọgbẹ oriṣiiriṣii lara rẹ.

Lasiko yii si ree, Alukoro sọ pe boya yoo ku tabi yoo ye ni mama naa wa lọsibitu (Danger list), nitori yatọ si pe wọn yinbọn fun un ti atanpako osi rẹ si ge danu lori ere, awọn Fulani naa tun ṣa a ladaa kaakiri ara, iyẹn lo si fa ọgbẹ oriṣiiriṣii to wa lara obinrin naa.

Oko ni iya yii n lọ nigba to ṣalabapade awọn Fulani ọhun, inu mọto rẹ lo wa lasiko to ri awọn maaluu rẹpẹtẹ. Ara fu u, o si fẹẹ ṣẹri mọto rẹ pada, ṣugbọn niṣe lawọn Fulani naa ya jade lati inu igbo, wọn yinbọn si taya mọto rẹ mẹrẹẹrin ko maa baa le lọ mọ, awọn taya naa jo lẹsẹkẹsẹ, nigba naa lawọn Fulani ọhun dana ibọn bo iya yii, ti wọn tun ṣa a ladaa mọ ọn.

Atanpako osi pẹlu àgbọǹ iya to n jẹ Morunkeji yii ni wọn yinbọn mọ ọn, bi ko si jẹ pe Ọlọrun ni ẹmi rẹ i lo ni, awọn to yinbọn fun un ko fẹ ko ye rara, nitori wọn tun n yẹ ẹ wo ninu mọto naa pe boya o ti ku, bẹẹ naa ni wọn si n pe e wo lati mọ boya ẹmi ti bọ lara ẹ.

Nitori mama yii pirọrọ fun wọn bii ẹni to ti ku loootọ ni wọn ṣe fi i silẹ ti wọn sa wọgbo lọ, ko too di pe iya naa pada ri aanu gba latọwọ awọn ọlọkọ mi-in to n kọja, ti wọn gbe e lọ sọsibitu bii meji n’Ijẹbu, ti wọn ko gba a nibẹ, ki wọn too waa gba a l’Ekoo, ni jẹnẹra to wa n’Ikẹja.

Ṣugbọn titi ta a fi pari iroyin yii, ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun, ni Abilekọ Morounkeji Salami wa.

Leave a Reply