Ọwọ ọlọpaa ti tẹ Titilayọ to lu ọmọ rẹ ta ni gbanjo l’Akurẹ, lo ba ni iṣẹ esu ni

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Abilekọ kan, Titilayọ Ikudaisi, lọwọ tí tẹ nibi to ti n gbiyanju ati lu ọmọ to bi ninu ara rẹ ta ni gbanjo.

Ọmọbinrin ọhun ni wọn ṣafihan rẹ pẹlu awọn afurasi ọdaran mi-in ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Titilayọ la gbọ pe ọwọ awọn ọlọpaa tẹ lẹyin to ta ọmọ ọdun kan to bi fun ẹnikan ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira.

Ṣe lọmọbinrin ọhun kọkọ daju gbau nigba ti akọroyin ALAROYE n fọrọ wa a lẹnu wo, tí ko si ṣe bii ẹni kabaamọ rara fun iwa to hu naa bo tilẹ jẹ pe o pada sọ fun wa pe esu lo ti oun lati gbe iru igbesẹ ti oun gbe naa.

O ni imọran ọrẹ oun kan loun tẹle ti oun fi lọọ gbe ọmọdekunrin naa ta lowo pọọku.

Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bọlaji Salami, ti ni o di dandan ki Titilayọ foju bale-ẹjọ ni kete ti iwadii bá ti pari lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Leave a Reply