Ọwọ tẹ Ṣakiru, alaga kansu tẹlẹ to gbe egboogi oloro l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

 NDLEA, ajọ to n gbogun ti gbigbe egboogi oloro nilẹ wa (National Drug Law Enforcement Agency) sọ pe ọwọ awọn ti ba afurasi ọdaran kan to ti figba kan jẹ Igbakeji alaga kansu Lagos Island nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Aṣekun Kẹhinde Ṣakiru, wọn lọkunrin naa ni baba isalẹ fawọn arufin to n ṣowo egboogi oloro.

Papakọ ofurufu Muritala Mohammed lọwọ awọn ẹṣọ NDLEA ti ba afurasi ọdaran ọhun nigba to fẹẹ wọ baaluu Virgin Atlantic Airline ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ ọjọ Satide to kọja, ilu London, lorileede UK lo loun n lọ.

Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, alaboojuto ẹka iroyin fun NDLEA sọ pe o ti pẹ tawọn ti wa Ṣakiru, wọn lọpọ awọn afurasi ọdaran to wa lakolo awọn ti wọn n ṣiṣẹ iwadii lori wọn lọwọ ni wọn n darukọ ọkunrin naa pe oun ni baba isalẹ awọn, oun lo n ran awọn niṣẹ, lo si n fun awọn lowo, wọn loun lawọn n ṣiṣẹ fun.

Eyi lo mu kawọn ọtẹlẹmuyẹ bẹrẹ si i fimu finlẹ lati mu ọkunrin naa ki wọn le gbọ tẹnu ẹ, ṣugbọn wọn ni bọrọ bọrọ lo n yọ mọ wọn lọwọ.

Bi Ṣakiru ba tiẹ fẹẹ sẹ kanlẹ pe niṣe lawọn to darukọ oun purọ mọ oun, ọrọ naa ko ṣee pa mọ bayii, tori wọn ni lasiko tọwọ ṣinkun ofin fi to o, ti wọn yẹ baagi to ko aṣọ atawọn nnkan eelo rẹ si wo, kilogiraamu kokeeni ni wọn lo tọju pamọ sibẹ.

Ko deede fi i pamọ bẹẹ naa o, niṣe ni Ṣakiru fi la silipaasi tuntun mẹwaa, aarin foomu bata ọhun ni wọn lo pin ẹru ofin si, to si fi gọọmu lẹ ẹ pa debii pe, yatọ si ẹrọ atanilolobo to taṣiiri pe ẹru ofin wa ninu baagi ọkunrin yii, ko sẹni to le fura pe bata lasan kọ lọkunrin naa fẹẹ gbe kọja ẹnubode.

Nigba ti wọn bẹrẹ iwadii, wọn lọkunrin to ti ṣe igbakeji alaga kansu fun saa meji yii jẹwọ pe loootọ loun mọ Azeez Adeniyi Ibrahim, afurasi kan ti wọn ka kokeeni mọ lọwọ loṣu kejila, ọdun to kọja.

Wọn lo sọ pe oniṣowo gidi loun, mọto loun n ta, ṣugbọn ko le ṣalaye bi owo rẹpẹtẹ ṣe denu awọn akanti rẹ ni banki. Wọn ni miliọnu marunlelogoje naira ni wọn ti gba lọwọ ọkunrin naa.

Ṣa, iwadii ṣi n tẹsiwaju, wọn ni tiwadii ba pari ni Ṣakiru maa foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply