Ọwọ tẹ Abubakar atawọn ọrẹ ẹ ti wọn n ta burẹdi atoogun fawọn ajinigbe

Faith Adebọla

Loootọ ni pe bi ina ko ba l’awo, ko le jo goke odo, ọwọ awọn agbofinro ti ba mẹrin lara awọn agbodegba to n ba awọn janduku agbebọn lagbegbe Kaduna, lapa Oke-Ọya, ṣiṣẹ, wọn jẹwọ pe awọn lawọn n ta burẹdi, ounjẹ, oogun fun wọn, awọn si maa n ta wọn lolobo ibi ti wọn ti le ri awọn araalu ji gbe pẹlu.

Ọsẹ to kọja yii la gbọ pe ọwọ tẹ awọn afurasi ọbayejẹ mẹrẹẹrin naa lẹyin tolobo ti ta ileeṣẹ ọlọpaa nipa irinsi wọn tawọn eeyan fura si. Orukọ wọn ni Abubakar Ibrahim tawọn eeyan mọ si Abu Riwaya (Rewire) lati abule Wasaba, ni Zaria, Auwal Abubakar ni ẹni keji, ilu Zaria loun n gbe, ẹni kẹta ati ẹkẹrin ni Hassan Magaji ati Ibrahim Kabiru tawọn eeyan mọ si Abba, abule Galadimawa lawọn mejeeji yii n gbe ni tiwọn.

Awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to lugọ de wọn lọjọ kẹjọ, oṣu kẹfa yii, lawọn afurasi naa ko sakolo wọn, nnkan bii aago marun-un aabọ irọlẹ niṣẹlẹ naa waye, nigba ti wọn n dari bọ latinu igbo ti wọn ti lọọ ta burẹdi atawọn nnkan eelo mi-in fawọn ajinigbe ninu igbo, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe wọn.

Nigba ti wọn wadii ọrọ lẹnu wọn, awọn afurasi ọdaran yii jẹwọ pe awọn lawọn ko burẹdi lọọ fawọn ajinigbe lawọn ibuba wọn ni Galadimawa, Damari, Kidandan ati Awala, ti gbogbo ẹ wa lagbegbe ijọba ibilẹ Birnin Gwari ati Giwa, nipinlẹ Kaduna.

Hassan Magaji jẹwọ pe iyawo meji atọmọ mẹta loun ni, o lọdun 2018 loun bẹrẹ okoowo burẹdi, tori ọkada loun maa n gun jẹun ṣaaju igba yẹn, ṣugbọn niṣe lawọn agbebọn saaba maa n lugọ de awọn, ti wọn si maa n fibọn gba ọkada lọwọ awọn.

O ni mọlẹbi oun kan, Mustapha Magaji, lo fọna okoowo burẹdi ṣiṣe han oun, loun ba tuwo jọ, oun si bẹrẹ.

“Ẹgbẹrun mọkanlelogun naira (#21,000) ni mo fi bẹrẹ, ṣugbọn ni bayii, mo n pa owo to to ẹgbẹrun lọna irinwo naira (#400,000) loṣu. Igba ti mo bẹrẹ si i sọpulai (supply) burẹdi fawọn agbebọn lowo nla bẹrẹ si i rọjo sapo mi.

Ilu Galadimawa nibi ni mo gbe dagba, mo si mọ awọn kan lara awọn ọdọ ta a jọ dagba ti wọn ti di agbebọn. Ọkan ninu wọn, Mohammed, lo fọna bi mo ṣe maa maa ta a fawọn agbebọn han mi.

Lọjọ ti mo pade Mohammed, burẹdi mẹwaa lo waa ra lọwọ mi nibi ti mo patẹ si, igba naira (N200) lo ra ọkọọkan dipo aadọsan-an naira (N170) ti mo n ta a, o si gba nọmba foonu mi. Lọjọ keji, o pe mi lori aago, o ni burẹdi mi dun lẹnu awọn gan-an, pe ki n ko ogun (20) si i wa.

Nigba ti mo ko o lọ, awọn mẹta ni wọn yọju si mi, wọn lawọn fẹẹ maa ra burẹdi pupọ lọwọ mi, ati pe awọn maa maa san asansilẹ owo fun mi ki n le rowo ṣowo ọhun, wọn bẹrẹ latori ẹgbẹrun lọna ogun naira (#20,000), kẹrẹkẹrẹ wọn n san asansilẹ ẹgbẹrun lọna aadọta naira (#50,000), igba to si ya, mo n gba ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira (#150,000) lasansilẹ owo burẹdi.

O lawọn kọsitọma ọran toun n taja fun yii ki i mu oun de ibi ti wọn wa gan-an ninu igbo, mọto ko tiẹ le debẹ tori ki i ṣe ọna mọto, tori naa, o nibi ti mọto oun maa duro si, ibẹ lawọn ti maa n pade, toun si maa ko burẹdi ti wọn sanwo ẹ silẹ fun wọn.

O loun tun ṣakiyesi pe nigbakuugba ti wọn ba ti lọọ jiiyan rẹpẹtẹ gbe, burẹdi ti wọn n ra maa n pọ si i, bii iru igba ti wọn ji awọn ọmọ fasiti kan gbe ni Kaduna, o niru asiko yẹn, burẹdi to to ẹgbẹrun lọna aadọrin naira (#70,000) loun maa n ta fun wọn lojoojumọ, ṣugbọn ni bayii, o ti dinku si ẹgbẹrun lọna aadọta lojumọ.

Awọn ọlọpaa tun bi i lere ohun to fi owo buruku to pa naa ṣe, o loun ko fi ṣe nnkan gidi kan ju pe oun fẹyawo tuntun lọ.

Ni ti Abubakar, oun jẹwọ pe loootọ loun naa n ta burẹdi fawọn agbebọn, o ni ṣugbọn ko sẹni ti ko mọ wọn pe agbebọn ni wọn, o ni ọpọ awọn araalu lo mọ wọn, ṣugbọn ko sẹni to maa wi kinni kan ni, niṣe lonikaluku n ṣọgba ẹ.

O sọ pe awọn agbebọn naa ki i wọ iboju ti wọn ba wa saarin ilu, o lawọn mọ abule wọn, o kan jẹ pe inu igbo kijikiji ni wọn n gbe bayii ni, wọn o ni mọlẹbi kan tori wọn o ki i fẹyawo tabi bimọ, awọn kọmandanti wọn nikan lo maa n fẹyawo ninu awọn obinrin ti wọn ba ji gbe, wọn si maa n bimọ.

Abubakar ni oun o mọ pe ko daa lati taja fawọn agbebọn naa afi igba tawọn ọlọpaa mu oun yii, o ni loju toun, oun ro pe oun n ṣọrọ-aje ni toun ni, tori awọn mi-in naa maa n taja fun wọn.

Afurasi mi-in, Ibrahim, ọmọ ọdun mẹtadinlogun pere, jẹwọ fawọn agbofinro pe niṣe loun ṣiwọ ileewe pamari to wa ni Galadimawa, nigba tawọn obi oun ko lagbara lati ran oun lọ mọ, loun ba dara pọ mọ wọn lẹnu iṣẹ agbẹ ti wọn n ṣe.

O loun ti kọkọ n tuwo jọ lati ra ọkada, tori oun ro pe okoowo mi-in toun le ri owo nidii ẹ yatọ siṣẹ oko ni ọkada gigun, ẹnu erongba yii si loun wa toun fi pade Magaji to fọna tita burẹdi han oun, o si n foun ni ẹẹdẹgbẹta naira (N500) loojọ.

O loun ki i ṣe agbẹbọn o, tori baba oun ti kilọ foun nipa wọn, o ni burẹdi loun n ta fun wọn, ko ju bẹẹ lọ.

Awọn ọlọpaa ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ yii.

Leave a Reply