Ọwọ tẹ afurasi ajọmọgbe l’Ado-Ekiti, oriṣiiriṣii nnkan ni wọn ba lọwọ rẹ

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori ọrọ obinrin kan, Abilekọ Kazeem Tawa, ti wọn fẹsun kan pe o fẹẹ ji awọn ọmọdebinrin mẹta kan gbe lagbegbe Bank Road, niluu Ado-Ekiti, lọsẹ to kọja.
Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, gan-an lọwọ tẹ Tawa lasiko to n ko awọn ọmọ naa lọ, tawọn eeyan agbegbe ọhun si fura si i. Nigba ti alaye rẹ ko jọ ara wọn lọrọ naa di nnkan mọ ọn lọwọ, kawọn ẹṣọ alaabo too mu un.
Ẹnikan to n gbe lagbegbe tiṣẹlẹ ọhun ti waye, iyẹn adugbo kan to wa lẹyin ileepo NNPC, sọ pe ṣe lobinrin naa n ko awọn ọmọ ọhun lati inu igbo kan si ekeji lasiko to fẹẹ dọgbọn ko wọn lọ, irin ẹsẹ ẹ lo si jẹ kawọn eeyan fura si i nitori o jọ pe ẹru n ba a.
Lasiko ti wọn da ibeere bo o lo han gbangba pe awọn ọmọ naa ko tiẹ mọ ọn ri, eyi lo jẹ kawọn ẹṣọ alaabo tete lọọ fi panpẹ ọba gbe e, kawọn eeyan ma baa lu u pa.
Alukoro ọlọpaa Ekiti, ASP Sunday Abutu, ṣalaye pe ọmọleewe lawọn ọmọ naa, alaye ti wọn si ṣe ni pe obinrin naa sọ pe kawọn ba oun gbe ẹru, awọn ko si kọkọ da a lohun, ṣugbọn nigba to ya lawọn ko mọ nnkan to n ṣẹlẹ mọ.
Abutu ni, ‘‘Awọn mẹkaniiki kan to wa nitosi ni wọn fura si Tawa, nigba ti wọn si beere ọrọ lọwọ ẹ, o ni awọn ọmọ oun ni. Nnkan pada yiwọ fun un nigba tawọn ọmọ naa sọ pe awọn ko mọ ọn ri.
‘‘Nigba ti ẹka to n gbogun ti ijinigbe nileeṣẹ ọlọpaa n fọrọ wa afurasi yii lẹnu wo, alaye ẹ ko nitumọ, bẹẹ ni ko le sọ nnkan to n ṣe lagbegbe tọwọ ti tẹ ẹ ati idi to fi ko awọn ọmọdebinrin ọhun.’’
Alukoro naa ni oriṣiiriṣii nnkan bii oogun abẹnugọngọ, bata ọmọde ati tagba, awọn nnkan jijẹ ati mimu atawọn nnkan mi-in lawọn ri lọwọ obinrin naa.
Ẹwẹ, ọkọ meji lawọn ọlọpaa gbe wa si agbegbe iṣẹlẹ ọhun lọjọ Ẹti, Furaidee, ṣe ni wọn si de Tawa lọwọ ati ẹsẹ nigba to n mu wọn kaakiri awọn igbo to wa nibi tọwọ ti tẹ ẹ.

Leave a Reply