Ọwọ tẹ ajinigbe meji nibi ti wọn ti fẹẹ gbowo itusilẹ lori ọmọ ọdun meje l’Agbara

 Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ajinigbe lawọn ọkunrin meji yii, orukọ wọn ni Muhammed Abubakar; ẹni ọdun mejilelogoji (42), ati Clinton Niche; ẹni ọdun mejidinlogun (18). Ọjọ Aiku, Sannde, ti i ṣe ọjọ kẹta, oṣu kẹwaa yii, lọwọ ba wọn nibi ti wọn ti fẹẹ gbe miliọnu kan naira owo itusilẹ ti wọn fẹẹ gba lori ọmọ ti wọn ji gbe. Àgbárá, nipinlẹ Ogun, lọwọ ti ba wọn.

Ohun to ṣẹlẹ gan-an gẹgẹ bi baba ọmọ ti wọn ji gbe, Ọgbẹni Stephen Ajibili, ṣe ṣalaye fawọn ọlọpaa ni pe iya ọmọ naa lo ran an niṣẹ ni nnkan bii aago mọkanla kọja ogun iṣẹju ọjọ naa, n lawọn ajinigbe ba ji ọmọ ọhun torukọ ẹ n jẹ Daniel Ajibili, gbe.

O ni ko pẹ ti wọn fi pe oun pe boun ba fẹẹ ri ọmọkunrin tọjọ ori rẹ ko ju ọdun meje lọ naa gba pada laaye, afi koun fi miliọnu kan naira ranṣẹ sawọn.

Eyi lo mu Baba Daniel lọọ sọrọ naa fun wọn ni teṣan ọlọpaa Agbara, CSP Kayode Shedrack, Adele ọlọpaa agbegbe naa, si ko awọn eeyan rẹ sodi, wọn bẹrẹ iwadii lori ibi ti awọn ajinigbe naa sọ pe ki wọn gbe owo ọhun wa.

Nigba ti Ọlọrun yoo si ba wọn ṣe e, ajinigbe to n ba awọn obi ọmọ naa sọrọ jade wa pẹlu ẹnikeji rẹ lati gbe owo ti wọn fẹẹ gba, awọn ko mọ pe awọn ọlọpaa ti lugọ de wọn nibi kan.

Nibi ti awọn meji yii ti fẹẹ gbe owo naa lawọn ọlọpaa ti bo wọn, ni wọn ba mu wọn ṣinkun.

Awọn meji yii, Muhammed Abubakar ati Clinton Niche, ni wọn mu awọn ọlọpaa lọ si ibi igi ti wọn de ọmọ kekere naa mọ.  Aṣe mẹta tilẹ ni awọn ajinigbe naa, wọn fi ẹni kan ṣọ ọmọ ti wọn ji gbe, awọn meji jade lati lọọ gbe owo ni.

Nigba ti ẹni ti wọn fi ṣọ ọmọ naa kofiri pe wọn ti mu awọn eeyan oun silẹ loun ti sa lọ ni tiẹ, awọn ọlọpaa ko ti i ri i mu titi ta a fi pari iroyin yii.

Ṣugbọn awọn meji tọwọ ba yii jẹwọ ṣa, wọn ni mẹta lawọn, ara lo fu ẹnikẹta to fi sa lọ.

Adele ọlọpaa agba nipinlẹ Ogun, DCP Abiọdun Alamutu, paṣẹ pe ki wọn gbe awọn meji yii lọ sẹka to n ri si ijinigbe nipinlẹ yii, ki wọn si wa ẹnikẹta to sa lọ naa ri nibi yoowu ko sa lọ.

Leave a Reply