Ọwọ tẹ Akinyẹmi l’Ondo, ọmọ bibi inu ara rẹ lo n fipa ba lo pọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọwọ ọlọpaa Ẹnu-Ọwa, to wa niluu Ondo, ti tẹ ọkunrin ẹni ọdun marundinlaaadọta kan, Akinyẹmi Akintoroye, fun fifipa ba ọmọ bibi inu ara rẹ, Adenikẹ, lo pọ.

Baba ọlọmọ kan ọhun ni wọn fi pampẹ ofin gbe lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lẹyin tawọn olukọ ileewe alakọọbẹrẹ ti ọmọbinrin ẹni ọdun mejila naa n lọ lọọ fẹjọ rẹ sun pe o n fipa ṣe ‘kinni’ fun ọmọ rẹ.

Ninu alaye ti ọmọbinrin ọhun ṣe f’ALAROYE nigba ta a n fọrọ wa a lẹnu wo, o ni ọmọ ọdun mẹfa pere loun nigba ti mama oun ti ku, to si jẹ pe ọdọ baba oun loun n gbe latigba naa titi ti iṣẹlẹ ta a n sọrọ rẹ yii fi waye.

Nnkan bii ọdun kan sẹyin lo ni baba oun ti bẹrẹ aṣa fifipa ba oun sun ni alaalẹ niwọn igba to jẹ pe ori ibusun kan naa lawọn jọ n sun ninu ile ti awọn n gbe.

O ni laipẹ ni iya baba oun, Abilekọ Akintoroye, waa mu oun sọdọ nigba to fura iru ajọṣepọ to n waye laarin awọn, ṣugbọn ti baba oun tun waa fipa wọ oun pada wa sile.

Ọmọbinrin ọhun ni ọsan ọjọ kan lawọn deedee ri baba oun pẹlu ada lọwọ rẹ, to si n halẹ pe afaimọ ki oku ma sun lọjọ naa ti wọn ba fi kọ lati yọnda ọmọ oun ki awọn jọ maa lọ sile.

Ọkan ninu awọn olukọ ileewe alakọọbẹrẹ St’ Peters, nibi ti Adenikẹ ti n kawe naa kin ọrọ ọmọdebinrin yii lẹyin ninu ọrọ to ba wa sọ.

Olukọ ohun ta a forukọ bo lasiiri ni iwa ati iṣesi rẹ toun ṣakiyesi pe o yipada loun fi pe e lati fọrọ wa a lẹnu wo.

O ni lẹyin ọpọlọpọ arọwa ni ọmọbinrin naa too jẹwọ foun itu ti baba rẹ n fi i pa ni alaalẹ, pẹlu ikilọ pe ko gbọdọ sọ ohun to n sẹlẹ laarin awọn fun ẹda alaaye kan ti ko ba fẹẹ ku.

O ni kayeefi lọrọ naa kọkọ jọ loju oun atawọn olukọ yooku, lẹyin-o-rẹyin lo ni awọn lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti fun igbesẹ to yẹ.

Ohun ta a gbọ lasiko ta a n ko iroyin yii jọ lọwọ ni pe Akinyẹmi si n ṣẹ kanlẹ ni agọ ọlọpaa ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo.

Wọn lo jẹwọ pe loootọ ni pe ori bẹẹdi kan naa loun ati Adenikẹ n sun, ṣugbọn ko sọrọ aṣiiri tabi ibaṣepọ to ju ti baba ati ọmọ lọ laarin awọn.

 

.

Leave a Reply