Ọwọ tẹ Aribisala, ogbologboo adigunjale to n yọ awọn eeyan Iwarọ Akoko lẹnu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ṣe ni idunnu ṣubu layọ fawọn eeyan ilu Iwarọ Ọka ati Ikarẹ Akoko, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, pẹlu bọwọ ṣe tẹ ogbologboo adigunjale kan, Akin Shina Aribisala atawọn ọmọ iṣẹ rẹ meji ti wọn n yọ awọn eeyan agbegbe naa lẹnu lati ọjọ pipẹ wa.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọpọ ile onile ni Aribisala atawọn ẹmẹwa rẹ ti fọ ni Iwarọ ati Ikarẹ Akoko, bẹẹ ni ọkada ọlọkada tí wọn ti ji gbe ko ni lonka.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lawọn ẹsọ alaabo atawọn ọdọ ilu ko ara wọn jọ, ti wọn si pinnu lati ṣawari awọn afurasi adigunjale to n yọ wọn lẹnu lọnakọna nibikibi ti wọn ba fara pamọ si.

Akitiyan wọn pada seso rere lọjọ ta a n wi yii pẹlu bọwọ ṣe tẹ Aribisala pẹlu meji ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ nibi ti wọn fi ṣe ibuba ninu aginju kan nitosi Iwarọ Akoko.

Ọkada mejila pẹlu awọn ẹru ẹru ẹlẹru mi-in ti wọn ji ko ni wọn ba ni ikawọ awọn afurasi ọhun lẹyin tọwọ tẹ wọn.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ọga ọlọpaa tesan Ikarẹ Akoko, Ọgbẹni Ade Akinwande, ni iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ ọhun.

O ni gbogbo ipa to wa ni ikawọ awọn lawọn n sa lọwọ lori bọwọ ṣe maa tẹ awọn ọmọ ẹgbẹ adigunjale yooku ti wọn raaye sa lọ lọjọ tí àwọn lọọ ka wọn mọ ibuba wọn.

Leave a Reply