Ọwọ tẹ awọn adigunjale mẹta ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Akolo ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, ni awọn afurasi adigunjale mẹta yii, Mohammed Bello, Abubakar Mohammed ati Mohamed Bello, wa bayii,  Mohammed Usman ati iyawo rẹ ni wọn lọọ digunja lole, ti wọn si tun ṣa wọn lọgbẹ ni ibugbe awọn Fulani kan, Gaa Oorsha, ni ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2022.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fi sita niluu Ilọrin, l’Ọjọbọ, Tọsidee, to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti salaye pe ṣe ni wọn gba ipe kan pe awọn adigunjale lọọ ka baale ile kan, Mohammed Usman ati iyawo rẹ, mọle ni Gaa Oorsha, wọn ṣa wọn lọgbẹ yannayanna, wọn si tun gbe owo sa lọ si inu igbo. O tẹsiwaju pe iwadii fihan pe Usman ti wọn lọọ digunja lole ṣẹṣẹ ta maaluu kan ti owo rẹ din diẹ ni miliọnu kan Naira ni.

Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, Cp Tuesday Assayomo, paṣẹ pe ki awọn ẹṣọ alaabo wa awọn afurasi ọdaran naa lawaari, eyi mu ki awọn ọlọpaa ati ẹgbẹ fijilante kan lugbo, ti wọn si ri mẹta mu ninu wọn pẹlu awọn ibọn ati ohun ija oloro lọwọ wọn, ṣugbọn ọga wọn patapata sa lọ.

Ọkasanmi ni iwadii n lọ lọwọ lori bi wọn yoo ṣe ri ọga awọn afurasi naa mu, ti wọn yoo si foju ba ile-ẹjọ laipẹ.

Eeyan mẹrindinlogun lo padanu ẹmi wọn nibi ijamba ọkọ oju omi lasiko ti wọn n lọ sile Ileya

Leave a Reply