Ọwọ tẹ awọn ajinigbe meji l’Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Meji ninu awọn ajinigbe to n ṣoro bii agbọn lagbegbe Akoko lọwọ awọn ẹsọ alaabo ti tẹ nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Awọn afurasi ọhun la gbọ pe ọwọ tẹ nibi tawọn ọlọpaa ati ọdẹ ibilẹ ti n gbiyanju ati ṣawari awọn gende meji ti wọn ji gbe lọjọ ọdun Itunu aawẹ lagbegbe Ikaram ati Akunnu Akoko.

Araalu kan lo kọkọ ṣakiyesi ọkan ninu awọn ajinigbe naa to dibọn bii were pẹlu aṣọ akisa to wọ sọrun ati ẹru nla kan to gbe sori, nigba to si fọrọ wa a lẹnu wo to ri i pe ọrọ da lẹnu rẹ saka lo sare pe awọn ọdẹ lati waa mu un nitori pe iṣesi rẹ mu ifura lọwọ.

Awọn nnkan ti wọn ri nigba ti wọn n tu ẹru rẹ wo ni kaadi ipọwo (ATM), apoti ọsẹ, awọtẹlẹ dudu ati aṣọ dudu to n wọ lasiko to ba fẹẹ ṣiṣẹ ibi bakan naa ni wọn tun fidi rẹ mulẹ nibi ti wọn ti n yẹ ara rẹ wo boya wọn le ri foonu pe ko ti i pẹ rara to ṣẹṣẹ ba obinrin kan lo pọ tan.

Ọkunrin naa ni wọn ti gbe e lọ si olu ileeṣẹ awọn ọlọpaa to wa ni Ikarẹ Akoko, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo lọwọ.

Ilu Ajọwa Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, lọwọ ti tẹ afurasi keji, kaadi idanimọ awọn ologun ati foonu olowo nla kan ni wọn ka mọ ọn lọwọ ni tirẹ.

Afurasi ọhun la gbọ pe wọn ti fa le awọn ọlọpaa tesan Oke-Agbe Akoko lọwọ fun ẹkunrẹrẹ iwadii.

 

Leave a Reply