Ọwọ tẹ awọn ajoji mejidinlogun pẹlu kaadi idibo ilẹ wa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọga agba awọn aṣọbode to n ri si iwọle-wọde nilẹ wa, ẹka ti ipinlẹ Ọyọ, Isah Dansuleiman, ti kilọ fawọn ajoji to wa nipinlẹ naa pe ki wọn ṣọra wọn gidigidi, ki wọn ma si ṣe gbidanwo pe awọn yoo kopa ninu eto idibo to n bọ lọdun 2023. O ni ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe ki i ṣe ọmọ ilẹ wa, ṣugbọn to fẹẹ gbiyanju lati dibo yoo fimu kata ofin.

Ikilọ yii waye pẹlu bi wọn ṣe ka kaadi idibo ilẹ wa mọ awọn ajoji bii mejidinlogun lọwọ lasiko ti wọn n lọ kaakiri ipinlẹ naa lati ṣawari iru awọn kọlọransi eeyan bẹẹ ninu oṣu Kẹwaa, ọdun yii.

Isah sọ eleyii di mimọ lasiko eto itaniji kan ti wọn ṣe nipa eto idibo to n bọ fun awọn alẹnulọrọ, eyi ti wọn pe akori rẹ ni ‘Eto idibo to muna doko ni Naijiria:Ohun ti wọn n reti lọwọ awọn ajoji ki o to di ọjọ ibo, lasiko idibo ati lẹyin idibo’, eyi to waye ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keji, oṣu Kọkanla yii.

Ọga awọn aṣọbode yii ni ọwọ awọn tẹ awọn ajoji naa pẹlu kaadi idanimọ Naijiria lasiko tawọn n fimu finlẹ kaakiri awọn agbegbe kan nipinlẹ Ọyọ. O ni ohun ti awọn ajoji naa ṣe jẹ iwa ọdaran, o si lodi si ofin ilẹ wa. Ọkunrin naa ni oju-ẹsẹ lawọn ti ju wọn loko pada si orileede ti onikaluku wọn ti wa.

O waa fi kun un pe ko si ajoji kankan, labẹ akoso bo ṣe wu ko ri, to gbọdọ kopa ninu eto idibo ọdun to n bọ, ati pe ajeji yoowu ti awọn ba ri kaadi idibo lọwọ rẹ yoo jẹ’yan rẹ niṣu.

O fi kun un pe awọn ti wọn n lo awọn ajoji naa mọ pe wọn o ki i ṣe ọmọ ilẹ wa, awọn kan n lo wọn fun ifẹ ara tiwọn lati gba kaadi idibo ni.

Dansuleiman waa kilọ pe awọn ajeji ko gbọdọ dibo, o ni ijọba faaye gba wọn lati maa gbe niluu ti wọn ba wa, ki wọn si ma ṣẹ sofin ibẹ, iyẹn ti wọn ba ni iwe lati gbeluu naa. Bẹẹ lo rọ awọn ti ko ba ti i waa ṣe atunṣe iforukọsilẹ wọn ki wọn waa ṣẹ bẹẹ, nitori gbogbo wọn lawọn yoo hu jade nibikibi ti wọn ba sa pamọ si.

Dansuleiman waa rọ awọn araalu lati fẹjọ ajeji ti wọn ba ri kaadi idibo lọwọ rẹ sun.

Leave a Reply