Ọwọ tẹ awọn akẹkọọ ileewe Akọka, ọbẹ ni wọn fi n gba mọto lọwọ awọn eeyan

Faith Adebọla, Eko

 Ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn gende meji ti wọn pe ara wọn lọmọleewe Federal College of Education (Technical) to wa l’Akọka, nipinlẹ Eko, Dare Williams, ẹni ọdun mẹtalelogun, Bethel Chukwuocha, ẹni ọdun mejidinlogun, ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla kan ni wọn fọbẹ gba lọwọ onimọto kọlọpaa too ri wọn mu.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Hakeem Odumosu, to ṣafihan awọn mejeeji fawọn oniroyin lọfiisi rẹ n’Ikẹja sọ pe alẹ ọjọ Aje, Mọnde, to kọja yii lawọn afurasi ọdaran mejeeji ṣiṣẹ laabi naa.

Odumosu ni wọn jẹwọ fawọn ọlọpaa pe ọbẹ aṣooro kan ati egboogi lẹbu kan ti wọn gbagbọ pe o le mu oorun kun ẹni ti wọn ba fẹ ẹ lu, lawọn lo fun Ọgbẹni Clement Aniegbe, onimọto ti wọn ja ọkọ rẹ gba ọhun.

Wọn ni Williams jẹwọ pe owo toun maa fi ra awọn irinṣẹ orin kikọ loun n wa, tori oun gbagbọ pe ẹbun orin wa lara oun, oun naa si fẹẹ lokiki bii Davido tabi Runtown, igba toun si ti wa iranlọwọ kaakiri ti ko sẹni to fẹẹ ran oun lọwọ loun ṣe ronu ati lọọ digunjale. O loun fọrọ naa lọ ọrẹ oun, Chukwuocha, lawọn mejeeji ba bẹ sita.

Ọmọkunrin yii ni ero awọn ni pe kawọn ta mọto tawọn gba naa, kawọn si fowo ẹ ra irinṣẹ ikọrin.

Odumosu ni oru ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, lawọn ọlọpaa to n kaakiri lati teṣan Sabo mu awọn afurasi naa lagbegbe Yaba, nibi ti wọn ti n wa mọto ti wọn ji ọhun, wọn n wa ibi ti wọn ti maa ta a si. Igba tawọn ọlọpaa da wọn duro, wọn kọkọ fẹẹ sa lọ, eyi lo mu kawọn agbofinro fi mọto wọn le wọn ba. Igba ti wọn si beere iwe ọkọ ati ẹri lati fi ẹni to ni mọto han, kantankantan ni wọn n sọ lẹnu, lakara ba tu s’epo.

Ṣa, awọn mejeeji ti wa lakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, iwadii gidi si ti n lọ lori ọrọ wọn. Laipẹ ni wọn maa foju bale-ẹjọ gẹgẹ bi kọmiṣanna ṣe wi.

Leave a Reply