Ọwọ tẹ awọn Fulani mẹta pẹlu nnkan ija oloro l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Ọwọ ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ awọn Fulani mẹta ti wọn ka awọn nnkan ija oloro ati oogun abẹnu gọngọ mọ lọwọ l’Akurẹ.

Awọn mẹtẹẹta ọhun, Salisu Abdullahi, Mamuda Adamu àti Tijani Alilu, ni wọn dibọn bi awọn to n fi ọmọlanke sa panti kaakiri adugbo kọwọ too tẹ wọn lagbegbe Ala, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii.

Salisu atawọn ẹmẹwa rẹ la gbọ pe wọn ha sọwọ awọn ọlọpaa tesan Ọda, lasiko ti wọn n ṣayẹwo awọn ọkọ ati ọkada to n gba agbegbe Ala kọja.

Ọkada ti wọn gun lawọn agbofinro naa kọkọ da duro, ibi tí wọn si ti n tú ẹru to wa ninu ọmọlanke tí wọn de sẹyin ni wọn ti ṣalabaapade awọn nnkan ija oloro ati ọpọlọpọ oogun laarin awọn panti ti wọn ko sinu rẹ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo, Ikoro ni awọn tọwọ tẹ ọhun ko ti i ri alaye to nitumọ ṣe lori awọn nnkan ija oloro tí wọn ba ni ikawọ wọn.

 

Leave a Reply