Ọwọ tẹ awọn Fulani obinrin to n ṣagbodegba fawọn ajinigbe l’Oke-Ogun

Olu-Theo Ọmọlohun, Oke-Ogun

Zainab Saleh, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, to ti bimọ meji nile ọkọ, ati ẹnikeji rẹ, Asana Nuhu, lọwọ ọlọpaa ilu Iṣẹyin ti tẹ, ti wọn si ti wa lakolo wọn bayii latari ẹsun pe awọn eeyan naa lawọn ajinigbe n ran niṣẹ lati lọọ maa ba wọn gbowo lọwọ mọlẹbi awọn ti wọn ba ji gbe.

Gẹgẹ bi ẹni to fiṣẹlẹ naa to wa leti ṣe wi, oru ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, lọwọ tẹ wọn nileetura kan to wa lọna Our Lady, niluu Iṣẹyin, lakooko ti wọn n dari bọ lati ibi iṣẹ buruku ọwọ wọn.

Wọn ṣalaye pe ni deedee aago mẹwaa si mọkanla alẹ lawọn afurasi naa ti wọn jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Zamfara maa n dari pada si otẹẹli ọhun, nibi ti a gbọ pe wọn gba yara si lati bii oṣu mẹta sẹyin lai jẹ ki awọn eeyan fura si wọn.

Wọn ni ko sẹni to n foju kan wọn lọsan-an, afi oru bii ọrọ, ni wọn n rin.

ALAROYE fidi ẹ mulẹ pe awọn araadugbo ti wọn fura si wọn ni wọn lọọ ta awọn agbofinro lolobo tọwọ fi pada tẹ wọn.

Lẹyin ti wọn de agọ ọlọpaa ni wọn jẹwọ pe awọn Fulani ajinigbe ti wọn n ṣọṣẹ loju ọna Ado-Awaye si Maya, titi de ilu Abẹokuta, nibi ti wọn ti n da awọn arinrin-ajo lọna lawọn n ṣiṣẹ fun.

Wọn ni lẹyin ti wọn ba ji awọn eeyan gbe tan, awọn ni wọn n ran lati lọọ gba owo itusilẹ lọwọ mọlẹbi ẹni ti wọn ba ji gbe.

Wọn tun jẹwọ pe awọn lawọn lọọ gba miliọnu mẹta Naira, owo itusilẹ, lọwọ mọlẹbi oniṣowo adiẹ ọmọ bibi ilu Ilero kan, Ọgbẹni Taiwo Alabi, ti wọn ji gbe ni bii oṣu mẹta sẹyin atawọn mi-in bẹẹ.

Ni bayii, okun ti gbe aparo wọn, wọn si ti fa wọn le awọn ọtẹlẹmuyẹ lọwọ fun iwadii kikun, ki wọn too taari wọn sile ile-ẹjọ.

Leave a Reply