Ọwọ tẹ awọn Fulani to n ji ọkada gbe n’Isẹyin

Olu-the Omolohun, Oke-Ogun

Meji lara awọn Fulani mẹta ti wọn fẹsun kan pe wọn n domi alaafia ilu lsẹyin ati agbegbe rẹ ru lọwọ pada tẹ l’abule Serafu ti ko fi bẹẹ jinna siluu Isẹyin, nipinlẹ Ọyọ.

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, lọwọ pada tẹ wọn lẹyin ti ikọ awọn agbofinro ati awọn ti adari Fulani agbegbe naa ran lati lọọ ṣewadii olori awọn adigunjale naa, Umar Bello, ba oun ati alupupu Bajaj to ji gbe.

Olori awọn Fulani agbegbe Oke-Ogun, Oloye Baani Abubakar, ṣalaye fakọroyin wa lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii pe deedee aago mẹjọ alẹ Ọjọbọ, Tọside, ni Baalẹ Abule Serafu, Oloye Taiwo Effo, ke soun lori foonu pe awọn kọlọransi eeyan kan n daamu awọn ara agbegbe naa lọwọlọwọ, ki Olori Fulani naa tete waa ran awọn lọwọ lati ri wọn mu.

Abubakar ni kia lawọn ọlọpaa ati ikọ fijilante ti lọ sibẹ, ti wọn si ṣawari wọn.

Ibẹ lọwọ ti ba Umar Bello, lo ba ṣalaye pe awọn mẹta lawọn ṣiṣẹ ole jija to waye lalẹ ọjọ naa, o darukọ Aliu Samah lati ilu Igbojaye, ati ẹnikan to pe ni Shuaibu. Abubakar sọ pe oju-ẹsẹ ti wọn jabọ foun lawọn ti pe Olori Fijilante ilu Igbojaye lati ran wọn lọwọ ki wọn le ri Aliu Samah, wọn si pada ri oun naa mu lọjọ Satide lẹyin ti wọn ti dọdẹ rẹ. Otẹẹli kan niluu Igbojaye lọwọ ti ba a.

Ni teṣan ọlọpaa, awọn afurasi ọdaran naa jẹwọ pe alupupu tuntun ti awọn alagbaro ati alagbaṣe ti wọn ti fi ọdun kan ṣiṣẹ gba lọwọ awọn ọga wọn, lawọn foju sun, tawọn n ji gbe.

A gbọ pe wọn ṣe ọpọ lara awọn alagbaṣe naa leṣe lasiko ti wọn kọ lu wọn, lara wọn si wa lọsibitu, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.

Ọga ọlọpaa Isẹyin ti lawọn maa taari awọn tọwọ ba yii si olu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, lẹyin tiwadii ba ti pari, awọn yoo si maa dọdẹ awọn kọlọransi ẹda to ku.

Leave a Reply