Ọwọ tẹ awọn meji ti wọn sa lọgba ẹwọn Kuje 

Adewale Adeoye

Awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn kan ti wọn n pe ni ‘Kuje Correctional Centre’ to wa niluu Abuja, ti sọ pe meji lara awọn ẹlẹwọn kan ti wọn sa kuro lọgba ẹwọn ọhun lọwọ awọn ti tẹ pada bayii, tawọn si ti ju wọn sinu ọgba ẹwọn naa pada, ki wọn le maa jiya ẹṣẹ ohun to gbe wọn debẹ lọ.

Awọn mejeeji naa ni, Ọgbẹni Atiku Ibrahim, ẹni ọdun mẹtadinlogoji, ati Adamu Ibrahim, ẹni ogoji ọdun.

ALAROYE gbọ pe awọn ọlopaa ipinlẹ Adamawa ni wọn ri awọn ọdaran mejeeji naa mu nibi ti wọn sapamọ si, ti wọn si lọọ fọwọ ofin mu wọn. Lẹyin naa ni wọn fa wọn le awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn Kuje lọwọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa, SP Suleiman Nguroje, to fidi iṣelẹ naa mulẹ sọ pe awọn owuyẹ kan ni wọn waa ṣofoofo ibi tawọn ọdaran naa sapamọ si fawọn ọlọpaa, tawọn si tete tara ṣaṣa lọọ fọwọ ofin mu wọn ko too di pe wọn tun sa kuro nibi ti wọn wa naa. O ni awọn ti taari wọn si ọgba ẹwọn Kuje, nibi ti wọn ti sa kuro.

 Bẹ o ba gbagbe, ọjọ karun-un, oṣu Keje, ọdun 2022, ni awọn agbebọn kan lọọ kogun ja ọgba ẹwọn Kuje yii, ti wọn si tu awọn ẹlẹwọn ti wọn le ni ẹgbẹrin silẹ pe ki kaluku wọn maa lọ sile wọn. Ọpọ ninu awọn ẹlẹwọn ọhun ti wọn ti mọ pe ọwọ ṣi maa tẹ awọn wọn ko kuro ninu ọgba ẹwọn naa rara. Bẹẹ lawọn kọọkan ti wọn ti sa lọ tẹlẹ tun pada wa sinu ọgba ọhun funra wọn. Nigba ti awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn naa tun lọọ fọwọ ofin mu awọn kọọkan nibi ti wọn sapamọ si.

Leave a Reply