Ọwọ tẹ awọn ọmọ ‘yahoo’ mejilelọgbọn niluu Ogbomọṣọ, akẹkọo fasiti lo pọ ninu wọn

Owe Yoruba kan lo sọ pe ọjọ gbogbo ni tole, ṣugbọn ọjọ kan bayii ni tolohun. Owe yii lo ṣe rẹgi pẹlu awọn ọdọkunrin mejilelọgbọ kan ti ọwọ ileeṣẹ to n ri si iwa ibajẹ ati ajẹbanu lorileede yii (EFCC), tẹ niluu Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ, ti wọn si ṣafihan wọn ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni olu ileeṣẹ wọn to wa niluu Ibadan.

ALAROYE gbọ pe lasiko ti awọn EFCC ya bo ibuba wọn niluu Ogbomọṣọ lọwọ tẹ awọn ọdọ mejilelọgbọn ti wọn ni jibiti ori ẹrọ ayelujara ni wọn fi n ṣiṣẹ ṣe ọhun.

Mẹta ninu wọn ni wọn jẹ akẹkọọ-jade yunifasiti, ti wọn n sin ijọba lọwọ, nigba ti mọkandinlogun ninu awọn ọdọ naa jẹ akẹkọọ ni awọn yunifasiti kaakiri ilẹ wa, ti awọn mẹwaa to ku si jẹ oniṣẹ ọwọ.

Awọn eeyan naa ni Oyebamiji Francis; Aremọ Jeremiah; Ogbonnaya Prosper John; Anuoluwapọ Matthew; Ọladele Victor; Mumuni Waliyullah; Ọlawọyin Abiọdun; Oluwatoyin Henry; Ariṣekọla Shina; Babarinde Solomon; Samson Gideon; Joshua Ọla Adebayọ; Ajayi Joseph Ajibọla; Garba Mojeed, Ọlatunbọsun Tobilọba and Azeez Ridwan.

Awọn yooku ni: Ajala Timilẹhin; Adebọlapọ Bakare; Alaba Gideon; Ogunkẹyẹ Olumide; Ogunleke Tolu; Ọlapade Emmanuel; Adegoke Aanu Abiọdun; Job Ayantoye; Oyebọde Pẹlumi; Babayanju Toluwani; Ọladele Ayọbami; Omonaiye Abubakar; Sattong Baking; Abisoye Kẹhinde, Iwajọmọ Nathan and Aniyikaye Tọpẹ.

Oriṣiiriṣii awọn ọkọ igbalode olowo nla, awọn foonu olowo nla, ẹrọ alaagbeletan atawọn iwe ti wọn fi n lu awọn eeyan ni jibiti ni wọn ba nikaawọ wọn.

Ileeṣẹ naa ti ni awọn yoo foju wọn ba ile-ẹjọ lẹyin iwadii awọn

One thought on “Ọwọ tẹ awọn ọmọ ‘yahoo’ mejilelọgbọn niluu Ogbomọṣọ, akẹkọo fasiti lo pọ ninu wọn

Leave a Reply