Ọwọ tẹ awọn ọmọ ‘Yahoo’ mẹrin to fi Aminat ṣoogun owo ni Ṣagamu

Gbenga Amos, Ogun
 
Yoruba bọ, wọn lọmọ ẹni ku san ju ọmọ ẹni sọnu lọ, bi obinrin ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn kan, Aminat Adebayọ, ṣe ṣadeede poora niluu Ṣagamu, lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, to si ṣe bẹẹ dẹni awati bii abẹrẹ to bọ s’okun, lo fa a tawọn ọlọpaa ọtẹlẹyẹmuyẹ fi lọọ fimu finlẹ lagbegbe naa, tọwọ wọn si ba awọn afurasi ọdaran mẹrin, Azeez Raimi, ẹni ọdun mọkanlelogun, Micheal Awodẹrọ, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, Saheed Yusuf, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, ati Lateef Ṣonẹyẹ, ẹni ọdun mọkandinlogoji, wọn nipasẹ wọn lobinrin naa ṣe sọnu, awọn ni wọn mọ bi wọn ṣe ran an lajo alọọde.
Alaye ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe lori iṣẹlẹ yii ninu atẹjade kan to fi sọwọ s’ALAROYE ni pe ẹgbọn Aminat kan, Ahmed Adebayọ, lo kegbajare wa sẹka ileeṣẹ ọlọpaa Ṣagamu, lọjọ keji ti wọn ti n wa aburo rẹ ti wọn o ri i.
Lọgan ti wọn ti fiṣẹlẹ naa to Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, leti, lo ti paṣẹ fawọn ọtẹlẹmuyẹ kan lolu-ileeṣẹ wọn to wa l’Eleweẹran, l’Abẹokuta, lati kọja si agbegbe naa, ki wọn lọọ wadii bi agbalagba obinrin naa ṣe dawati, SP Taiwo Ọpadiran lo ṣaaju awọn ọtẹlẹmuyẹ ọhun.
Nibi tawọn atọpinpin yii ti n fimu finlẹ kiri pẹlu awọn imọ ẹrọ igbalode ti wọn ko dani, olobo ta wọn pe otẹẹli kan ti Ṣonẹyẹ Lateef ti n ṣiṣẹ, lawọn kan ti ri obinrin naa kẹyin.
Wọn de ọdọ Lateef lotẹẹli naa, o si jẹwọ fun wọn pe loootọ loun ri Aminat, o ni ọrẹ ẹ kan, Bọsẹ Fajẹbẹ, to wa si otẹẹli naa lọjọ ti wọn n sọ ọhun pẹlu ọrẹkunrin ẹ, ni Aminat yii tẹle wa.
Bọsẹ yii ni wọn lo pe Aminat lati ba oun de otẹẹli, nigba to debẹ, ti oun ati ọrẹkunrin ẹ wọ yara, Lateef ni oun jokoo pẹlu Aminat, ko maa ba jẹ oun nikan lo maa da wa, awọn si bẹrẹ si i sọrọ. Latori ọrọ kan si omi-in ni ọrọ ifẹ ti yi wọ ọ, tawọn si jọ gba lati maa fẹra. Ẹnu eyi lo lawọn wa ti Bọsẹ atọrẹkunrin ẹ fi ṣetan, wọn jade waa ba wọn, wọn si tun fi Aminat ati Lateef silẹ nibẹ,  wọn ba tiwọn lọ.
Lateef ni nigba to ya, Aminat naa ba tiẹ lọ, oun naa si kuro ni otẹẹli ọhun lọwọ alẹ, oun atawọn ọrẹ oun meji, Saheed Yusuf ati Micheal Awodẹrọ, lawọn jọọ kuro tori awọn ni adehun lati jọọ ṣabẹwo sọdọ baba adahunṣe kan, Azeez Raimi, to fẹẹ bawọn yẹ Ifa wo lori ọrọ kan to ru awọn loju, ibẹ si lawọn wa di aajin oru.
Ṣugbọn alaye Lateef yii ta ko ti Raimi, wọn ni baba adifala yii jẹwọ fawọn ọlọpaa pe obinrin ti wọn n wa yii wa pẹlu awọn mejeeji nigba ti wọn fi wọle sojubọ oun, o ni inu ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn gbe wa lobinrin naa jokoo si, ko tẹle wọn wọle, ṣugbọn nigba toun jade sita loru, oun ṣi ri obinrin naa ninu ọkọ wọn, nigba tawọn kọsitọma yii si ṣetan lọdọ oun, awọn atobinrin naa lawọn jọọ dagbere funra awọn.
Wọn bi Azeez boya o le da obinrin naa mọ to ba ri fọto ẹ, o loun le da a mọ, ni wọn ba fa fọto Aminat yọ, o si fidi ẹ mulẹ pe obinrin yii loun ri pẹlu wọn loootọ, wọn jọ kuro lọdọ oun ni.
Micheal Awodẹrọ naa jẹwọ pe loootọ ni, o ni Saheed, toun n jẹ ọmọ ‘Yahoo’, iyẹn awọn ti wọn n lu jibiti ori ẹrọ ayelujara, atobinrin naa ni wọn jọ kuro loru ọjọ ọhun pẹlu Lateef. Ọdọ adahunṣe yii loun sun ni toun, igba tilẹ si mọ, tawọn ọrẹ yooku pada waa ba oun nibẹ, awọn meji ni wọn wa, ko si obinrin naa pẹlu wọn mọ.
Oyeyẹmi ni iwadii tawọn ọlọpaa ṣe ti fihan pe afaimọ ni ki i ṣe pe wọn ti lo obinrin yii fun etutu ọla, o lafeeyan-ṣowo lawọn afurasi ọdaran yii.
O ni iṣẹ iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ yii, awọn yoo si tuṣu desalẹ ikoko lati mọ ibi ti Aminat ha si gan-a

Leave a Reply