Ọwọ tẹ awọn ọmọ ‘Yahoo’ mẹrinlelọgbọn l’Ọwọ, oriṣiiriṣii ọkọ ni wọn ba lọwọ wọn

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn ọmọ ‘Yahoo’ bii mẹrinlelọgbọn lọwọ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹ-ede yii, EFCC, tẹ niluu Ọwọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to pari yii.

Ọgbẹni Wilson Uwujaren to jẹ Alukoro ajọ naa fidi rẹ mulẹ fawọn oniroyin pe awọn ọmọ ‘Yahoo’ ọhun ni wọn wa ninu ẹgbẹ onijibiti kan ti wọn n pe ni Erinlẹ.

Orukọ awọn to ni awọn ṣi ri mu ninu awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni, Adesuyan Ayọọla, Oyesanmi Ṣọla, Adegbole Victor, Osagie Ekiende, Akinayọmide James, Okunade Jamilu,

Ọmọtọṣọ Oluwaṣeyi, David Oluwatobi, Ahmed Rilwan, Saheed Ọdunayọ, Ọlrọrunfẹmi Emmanuel ati Obakpolor Tommy.

Bakan naa ni awọn bii, Emmanuel Ibe, Temiloluwa Joshua, Victor Benjamin, Akinwale Oluwaṣeun, Ogunboye Dọtun, Adeniyi Fẹmi, Ọbademi Samson, Ọladunjoye Tẹniọla, Eze Raphael, Samson Fadugbagbe pẹlu Oguntimẹhin Bamidele.

Awọn yooku ni, Moshood Kazeem, Oniye Damilare, Balogun Mayọwa, Ọbadapọ Wale, Ese Stephen, Atakili Pẹlumi, Adesumọ Fatai, Ọlalekan, Demi Temidayọ, Ọṣọrun Joseph ati Oluwafẹmi Damilọla Michael.

Awọn ẹru bii ọpọlọpọ kọmputa agbeletan, ọkọ olowo nla, foonu loriṣiiriṣii, kaadi idanimọ atawọn nnkan mi-in to lodi sofin lo ni awọn ka mọ wọn lọwọ.

O ni gbogbo wọn lawọn ti fi ṣọwọ si olu ileesẹ awọn to wa niluu Benin, nipinlẹ Edo, nibi ti wọn ti n fọrọ wa wọn lẹnu wo lọwọ.

 

Leave a Reply