Ọwọ tẹ awọn ọrẹ mẹta to n ja ero inu ọkọ lole ni Koṣọfẹ

Jọkẹ Amọri

Ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ni tolohun, bẹẹ gẹlẹ lọrọ ri fawọn ọrẹ mẹta kan, Ṣẹgun Ọlaiya, ẹni ogun ọdun, Ayinde Waris, ọmọ ọdun mọkandinlogun ati Bashiru Mohammed, ẹni ọdun mejidinlogun ti wọn yan iṣẹ idigunjale laayo tọwọ twe ni nnkan bii aago meje alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii ni agbegbe Koṣofẹ, niluu Eko.

Awọn ero to ba wa ninu mọto tabi awọn ti wọn n fẹsẹ rin lọ ni wọn saaba maa n ja lole ni adugbo ibudokọ Ileewe  to wa ni oju ọna Ketu si Koṣọfẹ, loju ọna Ikorodu, ti wọn yoo si gba oriṣiiriṣii nnkan lọwọ wọn.  Lasiko ti wọn n da awọn eeyan lọna ti wọn n gbowo lọwọ wọn ni awọn ọlọpaa to n yipo agbegbe fun eto aabo ri wọn, ni wọn ba nawọ gan wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe awọn agbofinro lati agbegbe Ketu si Koṣọfẹ to n lọ kaakiri lo mu awọn olubi ẹda naa ni agbegbe ibudokọ Ileewe, ni Kosọfẹ, loju ọna to lọ si Ikorodu.  O ṣalaye pe awọn ọdaran mẹtẹẹta naa ti jingiri ninu ki wọn maa fipa ja awọn ero ọkọ lole, paapaa ju lọ ninu sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ. Iṣẹ yii kan naa ni wọn n ṣe lọjọ yii ti ọwọ fi tẹ wọn.

Benjamin sọ pe iwadii n lọ lọwọ lati mu awọn ẹlẹgbẹ wọn to ku ti wọn jọ n lọwọ si iwa ibajẹ yii. Bẹẹ lo sọ pe awọn ti ọwọ tẹ naa ko ni i pẹẹ foju ba kootu lati ṣalaye ohun ti wọn ri lọbẹ ti wọn fi waro ọwọ lori iwa idigunjale ti wọn n hu.

Leave a Reply