Owo tẹ ayederu dokita, ẹni to ṣiṣẹ abẹ fun lo ku 

Adewale Adeoye

Awọn ọlọpaa agbegbe Ọta, nipinlẹ Ogun, ti foju ayederu dokita kan, Afeez Adegoke, ẹni ̀ọdun marundinlogoji (35), to jẹ oludasilẹ ati alaṣẹ ọsibitu kan ti wọn n pe ni ‘Goodness Clinic’ to wa l’Ojule kẹfa, Opopona Eri-Antena, lagbegbe Onibukun, niluu Ọta, bale-ẹjọ Majisireeti to wa niluu ọhun.

Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o pe ara rẹ lojulowo dokita akọṣẹ-mọṣẹ iṣegun oyinbo, to si ṣiṣẹ abẹ fun Ọgbẹni Patrick Effiong, ti onitọhun si ku mọ ọn lọwọ lakooko to n ṣiṣẹ abẹ naa lọwọ.

 Ẹsun meji ọtọọtọ  ni wọn fi kan ayederu dokita ohun, ti wọn si sọ pe bo ba jẹbi awọn ẹsun naa, yoo pẹ lẹwọn ju ọbọ lọ.

Ninu ọrọ Agbefọba, Insipẹkitọ Bọla Owolabi, to foju afurasi ọdaran naa balẹ-ẹjọ lo ti sọ pe o parọ, to si pe ara rẹ lojulowo dokita akọṣẹ-mọṣẹ, leyii ti kì í ṣe bẹẹ. 

Bakan naa kan lo tun lo iwa aibikita rẹ yii lati fi ṣeku pa Oloogbe Patrick lakooko to n ṣiṣe abẹ fun un. Gbogbo awọn ẹsun wọnyi ni wọn sọ pe ijiya nla lo wa fẹni to ba ṣe e labẹ ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ogun n lo.

Lẹyin ti wọn ka gbogbo ẹsun ọhun si i leti, Moses loun ko jẹbi, o waa rawọ ẹbẹ si adajọ ileejọ naa pe ko ṣaanu oun.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ  O.L. Oke, gba beeli rẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (N500,000), pẹlu oniduuro mẹrin ọtọọtọ, ti wọn lohun ti wọn fi le duro ti dọkita naa ba sa lọ ko too di akoko igbẹjọ rẹ. 

Lẹyìn eyi lo sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.

Leave a Reply