Ọwọ tẹ ayederu lọọya to tun n pe ara ẹ lọba l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti tẹ ọkunrin kan, Rufus Ajayi, ẹni aadọta ọdun to n pe ara ẹ ni agbẹjọro ati ọba ilu Gbomina, nipinlẹ Kwara.

Ajayi to jẹ ọmọ bibi ilu Rore, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, ni Kwara, lawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ mu laafin Ewi ti Ado-Ekiti, Ọba Rufus Adejugbe, nigba ti wọn ni o fẹẹ lu ọba naa ni jibiti.

Ohun ti Rufus waa sọ fun Ewi Ado gẹgẹ ba a ṣe gbọ ni pe oun fẹẹ ko awọn ọba ipinlẹ Ekiti ti ko din lọgọrun-un jọ lati lọọ ṣepade kan l’Abuja.

O ni oludije funpo aarẹ kan lọdun 2023 ni awọn yoo jọ ṣepade ọhun. O si sọ fun kabiyesi pe ọba loun naa, ọba ilu Gbomina, ni Kwara.

Koda, ọkunrin naa tun ṣe patako atọka agbelẹrọ kan ti aworan oun ati Ewi wa, to fi kede ipade rẹ naa. Bo ṣe gbe patako ajuwe yii wọ aafin Ewi ni awọn oloye ọba yii ti gbe e lọọ han Kabiyesi lati mọ boya loootọ ni ipade yii fẹẹ waye.

Lọgan ti Ọba Adejugbe ri patako yii lo ti ni oun ko mọ nnkan kan nipa ẹ, o si paṣẹ pe kawọn ọlọpaa waa fi panpẹ ofin mu Ajayi, ko le lọọ ṣalaye idi to fi n pete ipade awuruju.

Awọn ọlọpaa beere lọwọ ẹ nipa ipade rẹ naa, Rufus ko ri alaye gidi ṣe. Ọba  Ewi paapaa wo o titi, o si sọ fawọn ọlọpaa pe oun fura si aṣọ ati ade to de sori ninu patako to fi kede ipade rẹ naa.

Kabiyesi Ewi sọ pe, “Logan ti mo ri aṣọ ati ade to de sori pẹlu ilẹkẹ to lo sọrun ni mo ti mọ pe eleyii ki i ṣe ọba. Mo ti kọkọ beere lọwọ awọn ijoye mi boya a ri ọba kankan nilẹ Yoruba to n lo iru ilekẹ gigun bii ti ọrun Ajayi, ilẹkẹ ti wọn n lo lapa Oke-Ọya laye atijọ ni. Gbogbo wọn naa lo ya lẹnu, wọn ni ayederu eeyan kan lọkunrin naa, o si jọ onijibiti ẹda. Eyi lo jẹ ki n pe ọlọpaa pe ki wọn ṣewadii to daju lori iru eeyan ti okunrin yii jẹ’’.

Ọga ọlọpaa Akerekan Usman, sọ pe loootọ ni Ewi pe awọn lati waa mu ọkunrin naa, awọn si ti bẹrẹ iwadii to daju lori ẹ.

O fi kun un pe Ajayi ko ṣalaye ara ẹ to fawọn lori ọrọ ọba to n pe ara ẹ, ṣugbọn o tun n pe ara ẹ ni agbẹjọro pẹlu. Ṣa, o lawọn ti taari rẹ si ilu Ilọrin fun itẹsiwaju iwadii.

Leave a Reply