Ọwọ tẹ baale ile mẹrin to ji ẹrọ amunawa MTN n’ Ijoko-Ọta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ṣinkun lawọn ọlọpaa mu awọn baale ile mẹrin yii, Clement Idenyi; ẹni ọdun mejilelogoji, Orogade Ọlalere; ẹni ọdun mọkanlelogoji, Ademọla Adekunle; ẹni ọdun mẹtalelaaadọta ati Tunde Adewale ti wọn ko sọ ọjọ ori tiẹ. Ẹrọ amunawa ti opo ileeṣẹ MTN n lo n’Ijoko-Ọta ni wọn ji gbe lai mọ pe awọn ọlọpaa to n dọdẹ wọn wa nitosi, bi wọn ṣe mu wọn ṣinkun lọjọ Sannde ọsẹ yii niyẹn.

Ṣaaju ni olobo ti ta DPO teṣan ọlọpaa Sango pe awọn kan ti pari eto lati ji jẹnẹretọ to wa l’Ojule keje, Opopona Akintunde, n’Ijoko-Ọta gbe, awọn ọlọpaa naa si ti n reti wọn.

Lọjọ kẹfa, oṣu kẹfa yii, ti i ṣe Sannde ọsẹ yii, ni nnkan bii aago marun-un idaji, awọn afurasi to fẹẹ ṣiṣẹ naa gbe mọto akẹru Hiab kan de, wọn si gbe jẹnẹretọ naa sinu ẹ, wọn fẹẹ maa lọ.

Nibi ti wọn ti n pete ati maa lọ lawọn ọlọpaa to ti lugọ de wọn ti yi wọn ka, bi wọn ṣe mu wọn ṣinkun niyẹn.

Nigba ti wọn n fọrọ wa wọn lẹnu wo ni wọn ri i pe Clement Idenyi to jẹ amojuẹrọ nibi ti wọn gbe ẹrọ ọhun si lo wa nidii ole jija yii, oun lo ṣeto bi wọn yoo ṣe waa gbe ẹrọ naa ti ẹnikẹni ko ni i fura.

Ni ti Tunde Adewale ni tiẹ, oun ṣeleri lati ra a lọwọ wọn bi wọn ba ri i jigbe ni, bẹẹ lo si fun wọn nidanilẹkọọ lori beeyan ṣe maa n ji ẹru ileeṣẹ bii eyi gbe ti ko ni i mu ẹjọ dani.

Ṣugbọn ọwọ palaba wọn segi pẹlu gbogbo ọgbọn ti wọn da naa, awọn ọlọpaa si pada ko wọn nibi ti wọn ti n ṣiṣẹ ibi naa lọwọ ni.

Iwadii n tẹsiwaju lori wọn gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fi to ALAROYE leti ṣe wi, wọn yoo si de kootu dandan basiko ba to.

Leave a Reply