Ọwọ ẹṣọ Amọtẹkun tẹ baba agbalagba to n ṣe agbodegba fawọn Fulani ajinigbe l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Baba ẹni ọdun marundinlọgọrin kan, Alaaji Ibrahim, lọwọ ẹsọ Amọtẹkun ti tẹ lori ẹsun pe o n ṣe agbodegba fun awọn Fulani ajinigbe kan to n yọ awọn eeyan ipinlẹ Ondo lẹnu.

Ninu alaye ti Alakooso ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ṣe fawọn oniroyin nigba to n ṣafihan awọn afurasi ọhun ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Alagbaka, lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, o ni nnkan bii oṣu mẹta sẹyin lawọn ti n lepa ikọ awọn ajinigbe ọhun kọwọ too pada tẹ wọn lopin ọsẹ to kọja.

Adelẹyẹ ni ọkan ninu awọn ajinigbe ọhun, Amadu Sede, lọwọ awọn kọkọ tẹ ninu igbo kan l’Akoko, ni nnkan bii oṣu mẹta sẹyin.

O ni awọn Amọtẹkun ko ti i kuro ninu igbo naa tawọn Fulani darandaran mi-in fi ya bo wọn pẹlu ọkan-o-jọkan nnkan ija oloro, ti wọn si n gbiyanju lati pa Sede tọwọ tẹ mọ awọn ẹṣọ aabo naa lọwọ.

Afurasi ajinigbe naa lo ni wọn kun bii ẹni kun ẹran pẹlu bi wọn ṣe sa a ladaa lapa rẹ ọtun, ti wọn si fẹrẹ ge apa ọhun ja, bakan naa ni wọn tun da ọgbẹ nla mi-in sori rẹ, to si jẹ pe ketekete lawọn n wo ọpọlọ rẹ nita.

Lẹyin tawọn ikọ ajinigbe ọhun ti sa lọ tan lo ni awọn sare gbe Sede lọ sileewosan kan fun itọju, nibi ti wọn ti ṣiṣẹ  abẹ fun un, ti wọn si tọju tẹ titi ti ara rẹ fi ya.

Ni kete ti ara rẹ ya tan lo jẹwọ gbogbo iṣẹ ibi ti wọn ti ṣe fawọn Amọtẹkun, oun funra rẹ lo tun ṣaaju wọn lọ si agbegbe ori omi, ni Ilajẹ, nibi tọwọ ti tẹ Alaaji Ibrahim to jẹ baba isalẹ ati olori wọn pẹlu awọn afurasi mẹta mi-in ti wọn jọ n ṣiṣẹ ajinigbe.

Awọn mẹta tọwọ tun tẹ ni Sulaiman Ibrahim to jẹ ọmọ Alaaji Ibrahim, Muhammed Bello ati Abdulwahab Saminu.

Oloye Adelẹyẹ ni ohun ti awọn fidi rẹ mulẹ ninu iwadii awọn ni pe awọn Fulani darandaran ọhun ko niṣẹ meji ju iṣẹ ajinigbe lọ, o ni ṣe ni wọn kan n fi maaluu ti wọn n da boju kawọn eeyan ma baa fura si wọn.

Awọn Fulani ọhun lo ni wọn yoo foju bale-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba ti pari lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Leave a Reply