Ọwọ tẹ Babatunde n’Idanre, ọmọọlọmọ lo gbe pamọ, lo ba n ṣe ‘kinni’ fun un

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Akinfala Babatunde, lori ẹsun pe o gbe ọmọdebinrin kan, Ọpẹyẹmi Akinọla, t pamọ n’Idanre.

Babatunde ni wọn tun fẹsun kan pe o fipa ba ọmọbinrin ẹni ọdun mẹtadinlogun ọhun sun laarin asiko to fi gbe e pamọ fawọn obi rẹ.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọmọkunrin ọhun ni wọn lo lọ sile awọn obi Ọpẹyẹmi to wa l’Ojule kin-in-ni, adugbo Molekere, ni Ododẹ Idanre, n’ijọba ibilẹ Idanre, ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun ta a wa yii, nibi to ti fọgbọn ẹwẹ tan ọmọ naa lọ sile ọdọ rẹ, eyi to wa laduugbo Agọsile, lai bun baba ati iya rẹ gbọ ko too ṣe bẹẹ.

Lẹyin ti wọn ti wa ọmọbinrin yii titi ti wọn ko ri i ni iya rẹ lọọ fohun to ṣẹlẹ to awọn agbofinro to wa ni teṣan Idanre leti, tawọn ọlọpaa si pada tọpasẹ ọmọ naa de ile Babatunde, nibi to ti n ṣe ‘kinni’ fọmọ ọlọmọ.

Nigba ti wọn n fọrọ wa ọkunrin naa lẹnu wo ni teṣan, o jẹwọ pe loootọ loun gbe Ọpẹyẹmi tira fun odidi ọjọ meji gbako, amọ ti ko sohun to jọ ọrọ ibara ẹni lo pọ laarin awọn mejeeji.

O ni ọrẹbinrin oun ni Ọpẹyẹmi, ati pe ọmọbinrin ọhun funra rẹ lo pe oun lori aago lalẹ ọjọ naa, to si ni oun n bọ nile oun.

O ni oun ko wulẹ tun maa beere lọwọ rẹ boya o sọ fawọn obi rẹ ko too wa tabi ko sọ fun wọn. Babatunde ni oun ko ri i gbọ lati ibikibi pe wọn ti n wa a nile, bẹẹ ni ki i ṣe pe oun tilẹkun mọ ọn tabi de e mọlẹ sinu yara oun.

Awọn ọlọpaa pada wọ ọmọkunrin naa lọ sile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Idanre lori ẹsun ijinigbe ati ṣiṣe ọmọ niṣekuṣe ti wọn fi kan an.

Awọn ẹsun ọhun ni Agbefọba, Ajiboye Ọbadaṣa, juwe bii eyi to ta ko abala okoolenigba le mẹfa (226) ati ọtelelọọọdunrun (360) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.

Lẹyin ti olujẹjọ ọhun ti ni oun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an, Onidaajọ F. A. Adesida faaye beeli ẹgbẹrun lọna aadọta Naira ati oniduuro meji ni iye owo kan naa silẹ fun un.

Olujẹjọ ọhun ni wọn ni ki wọn maa gbe lọ si ọgba ẹwọn Olokuta to wa niluu Akurẹ, nigba ti koko tete ri ọrọ beeli rẹ yanju.

Ọjọ kẹsan-an, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023, nile-ẹjọ ni igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.

Leave a Reply