Ọwọ tẹ gende yii, inu apo gaari lo ko ibọn atawọn ohun ija oloro si fawọn agbebọn 

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn ọlọpaa teṣan agbegbe Aguata, nipinlẹ Anambra, ni afurasi ọdaran kan tawọn ọlọpaa lawọn ko ti fẹẹ darukọ rẹ sita nitori ti iwadii ṣi n lọ lọwọ nipa rẹ wa, o n ran wọn lọwọ ninu iwadii wọn lori ẹsun ti wọn fi kan an pe o ko obitibiti ẹtu ibọn atawọn ohun ija oloro mi-in sinu apo gaari, o fẹẹ lọọ ko o fawọn agbebọn kan pe ki wọn maa fi dalu ru.

ALAROYE gbọ pe ikọ akanṣe awọn ọlọpaa agbegbe Aguata, nipinlẹ Anambra, lo fọwọ ofin mu un lẹyin tawọn araalu naa ta awọn ọlọpaa lolobo pe iṣẹ ọwọ afurasi ọdaran naa ko mọ. Bi wọn ṣe daa duro lọna ti wọn n beere ọrọ lọwọ rẹ ni ọrọ ẹnu rẹ ti n tase, ti ko si le ṣalaye ohun to ko pamọ sinu apo gaari naa fun wọn rara. Wọn yẹ inu awọn apo gaari ọhun wo daadaa, iyalẹnu lo jẹ nigba ti wọn ba obitibiti ẹtu ibọn atawọn ohun ija oloro mi-in nibẹ.

Oju-ẹsẹ ni wọn ti fọwọ ofin mu un ju sahaamọ wọn. Teṣan Aguata to wa lo ti jẹwọ pe agbodegba awọn agbebọn loun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Tochukwu Ikenga, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, sọ pe awọn araalu kan ni wọn ta ọlọpaa agbegbe naa lolobo, tawọn si d’ọde rẹ, ko too di pe ọwọ tẹ ẹ laipẹ yii. O ni lasiko ti afurasi ọdaran naa fẹẹ lọọ ko awọn ẹru ọwọ rẹ fawọn agbebọn lọwọ ọlọpaa tẹ ẹ.

Alukoro ni awọn n ṣiṣẹ lọwọ lori ọrọ afurasi ọdaran naa, awọn si maa foju rẹ bale-ẹjọ tiwadii ba ti pari.

Leave a Reply