Ọwọ tẹ Hamisu, mọto ajọ ẹsọ oju popo lo ji gbe l’Abuja

Oluyinka Soyemi

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa olu-ilẹ wa to wa niluu Abuja ti tẹ ọmọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn kan, Hamisu Tukur, lori ẹsun pe o ji mọtọ ajọ ẹṣọ oju popo (FRSC).

Gẹgẹ bi atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa naa, DSP Anjuguri Manzah, fi sita, mọto ti afurasi naa ji jẹ ti olu-ileeṣẹ ajọ ẹṣọ oju popo gan-an, eyi ti wọn gbe si agbegbe Wuse Zone 5.

Manzah ṣalaye pe ọjọ Abamẹta, Satide, ana, lọwọ tẹ Hamisu lẹyin ti ẹka eto ajọ to ja lole ọhun sọ fawọn ọlọpaa pe ẹnikan ti ji mọto awọn, nigba tawọn ọlọpaa si n yẹ ọkọ wo lagbegbe Bwari ni wọn mu ọkunrin naa.

O ni wọn gba mọto Toyota Hilux to ni nọmba HQ-26R ọhun lọwọ ẹ, wọn si ri i pe o ni kọkọrọ kan lọwọ to fi wa mọtọ naa.

Manzah waa sọ pe afurasi naa yoo jẹjọ iwa to hu nitori o ṣẹ si ofin, bẹẹ lo rọ awọn araalu lati maa fi to ọlọpaa leti ti wọn ba kẹẹfin awọn ọdaran bii Hamisu lagbegbe wọn.

Leave a Reply