Ọwọ tẹ Intercessor, ọkunrin to n ji iṣu awọn agbẹ wa ni Ṣaki

Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun

Latari pe ko si oniduuro fun un lẹyin ti wọn gba beeli rẹ nile-ẹjọ, Adajọ-agba I.O. Uthman tile-ẹjọ Majisreeti to wa niluu Ṣaki ti paṣẹ lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja, pe ki wọn da afurasi ọdaran kan, Ọgbeni Intercessor Upuu, ẹni ọdun mejilelọgbọn, to tun je ọmọ bibi ipinlẹ Benue, pada satimọle.

Ọjọ karun-un, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ni wọn taari ọkunrin to ni iṣẹ agbẹ loun n ṣe naa wa si kootu, wọn lo ji iṣu nla mẹwaa ati ọpọlọpọ agbado towo ẹ to ẹgbẹrun mẹwaa naira to jẹ ti Ọgbẹni Muritala Tijani.

Inspẹkitọ Abdulmumuni Jimba to jẹ agbefọba ṣe salaye nile-ẹjọ pe ni aarọ kutu ọjọ iṣẹlẹ yii lawọn fijilante to n ṣọ adugbo Odo Ẹrẹ, loju ọna Agọ-Arẹ, niluu Saki, kofiri afurasi naa nibi to ti n ṣiṣẹ laabi rẹ.

Bakan naa lawọn agbẹ agbegbe naa ti wọn jẹrii tako o lasiko igbẹjọ  sọ pe gbogbo igba ni awọn ire oko awọn maa n dawati, ṣugbọn awọn ko mọ pe ọkunrin ẹya Tiv yii lo maa n ji i, afigba tọwọ palaba rẹ segi, tawọn fijilante adugbo awọn ri i mu, ti wọn si foju rẹ han labule to n gbe.

Ẹsun ole jija ati biba nnkan oko oloko jẹ ni won fi kan an ni kootu.

Nigba tile-ẹjọ bi i leere boya o jẹbi, afurasi naa ko wulẹ fi akoko ṣofo to fi loun jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn ka soun lẹsẹ. Ọmọkunrin yii ni aanu ile-ẹjọ loun n bẹbẹ fun, ki wọn foju rere wo oun. O ni ọgbin paki ati wọta mẹlọọnu loun n ṣe.

Adajọ Uthman sọ pe to ba jẹ iwọnba iṣu tabi agbado ti olujẹjọ fẹẹ jẹ lo ji ni, ọrọ rẹ iba mọ niwọn, ṣugbọn ohun to ṣe ti fi han pe ole ati wọbia ẹda kan ni.

Ile-ẹjọ ni pẹlu bi afurasi ọdaran naa ṣe tete mọ ẹṣẹ rẹ lẹṣẹ yii, oun faaye beeli silẹ fun un, ṣugbọn ki wọn ṣi da a pada sahaamọ ọlọpaa titi di ọjọ kẹjọ, oṣu kẹwaa, ọdun yii, iyẹn bi ko ba rẹni gba beeli rẹ.

Leave a Reply