Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ iya ẹni ọdun marundinlọgọta (55) kan, Felicia Ademiloye, ati ọmọ rẹ ọkunrin, Adewumi Ademiloye, lori ẹsun pe wọn ji ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹẹẹdogun kan gbe ni ipinlẹ Ekiti.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ naa, Ọgbẹni Sunday Abutu, ṣalaye pe ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹẹẹdogun naa to jẹ ọmọ ileewe girama kan ni iya yii ati ọmọ rẹ ji gbe lati inu oṣu Kẹta, ọdun 2019.
Abutu ṣalaye pe ọmọdebinrin yii kuro nile laaarọ ọjọ naa lati lọ sibi to ti n gba ẹkọ fun idanwo oniwee mẹwaa (WAEC) ti o n mura lati ṣe ni akoko naa ti ko si pada wa sile lati igba naa.
O fi kun un pe iya ọmọdebinrin yii lo fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti lasiko naa, ti wọn si sa gbogbo ipa wọn lati ri ọmọdebinrin ọhun, ṣugbọn wọn ko ri i.
Abutu ṣalaye siwaju pe lẹyin ọdun kẹta ti wọn ti n wa ọmọ yii ni iya rẹ sọ pe oun gbọ lati ọdọ ẹnikan pe wọn ri ọmọ oun ni ọdọ awọn afunrasi naa.
Iya rẹ lo pada fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ẹka to n ri si ọrọ awọn ọmọ wẹwẹ leti. Lẹyin ti wọn bẹrẹ iwadii ati igbesẹ lati ri ọmọdebinrin to sọnu naa ni wọn ri i nile Felicia Ademiloye.
Lọgan ni wọn doola ọmọ yii, ti wọn si fi panpẹ ofin mu Felicia ati ọmọ rẹ ọkunrin, Adewumi, ẹni ọdun mejilelogun (22).
Ninu iwadii awọn ọlọpaa lo ti han pe Adewumi lo fọgbọn mu ọmọdebirin yii wọ inu ile wọn, to si fun un ni igbo ati egboogi oloro miiran mu, ti iyẹn ko si mọ ohun to n ṣe mọ.
Nigba ti ọmọ yii n ṣalaye ohun ti oju rẹ ri ni ọdun mẹta to ti lo nibi ti obinrin yii ati ọmọ rẹ gbe e pamọ si, o ni ni kete ti Adewumi fun oun ni igbo ati egboogi oloro ni gbogbo iye oun ti ra, ti oun ko si ranti ati pada sile mọ.
O ni lẹyin ti oun lo oṣu mẹfa lọdọ obinrin yii ati ọmọ rẹ loun di ẹni to n mu igbo ati egboogi loriṣiiriṣii.
Iwadii miiran tun fi han pe ọmọdebinrin yii ti loyun bii ọṣu mẹjọ sinu, ti ko si fi orukọ silẹ fun itọju nileewosan kankan.
Adewumi Ademiloye jẹwọ pe loootọ loun ṣẹ ẹṣẹ naa. Oun ati iya rẹ yoo foju bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba pari lori ọrọ naa.
Ọmọbinrin ẹni ọdun mẹẹẹdogun naa ti wa lọdọ awọn oṣiṣẹ ijọba to n ṣe amojuto fifi ipa ba ọmọde lo pọ fun itọju ati ayẹwo to peye.