Ọwọ tẹ meji lara awọn Fulani to maa n digun ja wọn lole l’Oro-Agọ

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni ajọ ẹṣọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, mu meji lara awọn Fulani ole to n yọ wọn lẹnu lagbegbe Oro-Agọ, nipinlẹ Kwara, iyẹn Abdullahi Ideh, ẹni ogun ọdun, ati Kadiri Babuga, ẹni ọdun mẹrinlelogun.

Alukoro ajọ naa, Ọgbẹni Babawale Zaid Afolabi, lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun awọn oniroyin niluu Ilọrin. O ni o pẹ ti awọn ọdaran naa ti n huwa ibi yii, maaluu ni wọn maa n gba lọwọ awọn Fulani darandaran, ti wọn yoo si sa lọ. Afọlabi ni ajọ NSCDC ti n dẹ wọn ọjọ ti pẹ, ṣugbọn ni bayii, wọn ti wa ni galagala ajọ naa.

Ninu ọrọ rẹ, o ni Fulani darandaran kan, Rawa Raura Muhammed, ni wọn da lọna pẹlu ibọn ati ohun ija oloro mi-in, ti wọn si ji maaluu rẹ mẹta gbe lọ, ti awọn maaluu naa to miliọnu kan aabọ naira niye.

Afọlabi tẹsiwaju pe Opopona Ahun-Ilkerin Ayuba, lọwọ ti tẹ wọn pẹlu ajọṣepọ ẹgbẹ Miyetti Allah, ẹgbẹ Vigilante ati akitiyan ajọ NSCDC. Awọn mẹta ni wọn, ṣugbọn ọkan torukọ rẹ n jẹ Baba Sanda, sa lọ mọ wọn lọwọ, awọn meji yooku tọwọ tẹ si wa ni ahamọ ni ọfiisi ajọ naa to wa ni Oro-Agọ. O fi kun un pe ajọ naa ti n dọdẹ ẹni kan to sa lọ, ti ọwọ yoo si tẹ ẹ laipẹ.

Leave a Reply