Ọwọ tẹ meji ninu awọn adigunjale to n daamu wọn l’Ogijo

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Meji ninu ikọ adigunjale kan ti wọn n daamu awọn eeyan Ogijo, nipinlẹ Ogun, lọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ bayii. Orukọ wọn ni Ọlaitan Oluṣọla (Tọshiba) ati Oluwajuwọn Balogun.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹwaa yii, lọwọ ba wọn lẹyin ipe kan ti teṣan ọlọpaa Ogijo gba pe ikọ adigunjale yii n ṣọṣẹ lọwọ lagbegbe Malatori, l’Ogijo.

Wọn ni ibọn lawọn ole naa yọ sawọn eeyan, ti wọn si n gba gbogbo ohun to ba wa lọwọ wọn.

Eyi lo mu DPO teṣan naa, CSP Muhammed Suleimọn Baba, ko awọn ikọ rẹ lẹyin lọ si Malatori, nibẹ lọwọ ti ba awọn meji yii, ti awọn yooku wọn si sa lọ.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ ọ di mimọ pe aake meji lawọn ọlọpaa ri gba lọwọ awọn meji tọwọ ba yii.

CP Edward Ajogun, kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, paṣẹ pe ki wọn ko awọn mejeeji yii lọ sẹka to n ṣewadii iwa ọdaran, ki wọn si wa awọn yooku wọn to sa lọ ri.

Leave a Reply