Ọwọ tẹ mẹrin ninu awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun to n paayan kiri n’Ilaro

Gbenga Amos, Abẹokuta

Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un yii, ẹgbẹrun Saamu awọn afurasi ọdaran to n yọ awọn eeyan agbegbe Ilaro, nipinlẹ Ogun, lẹnu ko ribi sa si mọ, ọwọ ṣinkun awọn agbofinro ba wọn lagbegbe naa, wọn si ti fi pampẹ ofin gbe wọn.
Orukọ awọn afurasi ti wọn fẹsun kan pe wọn n ṣẹgbẹ okunkun Aiye, ti wọn si tun ṣeku pa gende kan, Ọgbẹni Ṣẹgun Onifade, logunjọ, oṣu Kẹrin, to kọja yii, ni: Samson Jacob, ti wọn n pe ni Cybog, Iyanu Kazeem Akande, Ọmọọyami ni wọn mọ oun si, Adebayọ Adeoluwa, ti inagijẹ tirẹ n jẹ Dudu, ati ẹkẹrin wọn, Yusuf Adelakun.
Ba a ṣe gbọ, olobo kan lo ta awọn ọlọpaa ẹka ileeṣẹ wọn to wa n’Ilaro pe awọn afurasi ọdaran mẹrin naa n ṣepade imulẹ kan, oru ni wọn daṣọ boju ṣepade naa lẹyin ileewe alakọọbẹrẹ Ẹlẹja, to wa laduugbo Igbo-Ewe, niluu Ilaro.
Bawọn ọlọpaa ṣe gbọ ni wọn ti dihamọra, wọn si rọra lọ sibi ipade wọn ọhun, ṣinkun ni wọn mu awọn mẹrẹẹrin.
Lara nnkan ija oloro ti wọn fi n ṣọṣẹ ti wọn ba lọwọ wọn lọjọ naa ni ibọn ilewọ pompo meji, katiriiji ọta ibọn mẹrin ti wọn o ti i yin, aake kan, foonu alagbeeka olowo iyebiye marun-un, ọpọlọpọ oogun abẹnugọngọ, egboogi oloro naa ko si gbẹyin, wọn tun ba ọkada Bajaj ti wọn ko ni nọmba kan mọ wọn lọwọ.
Nigba ti wọn ko wọn de tọlọpaa, awọn afurasi ọdaran yii jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye lawọn, ati pe awọn lawọn n da omi alaafia agbegbe naa ru, nigba ti wọn ba fija pẹẹta pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun mi-in.
Ni ba a ṣe n sọ yii, akata wọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to n gbogun ti ṣiṣe ẹgbẹkẹgbẹ ni gbogbo wọn wa gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe wi ninu atẹjade rẹ.
O ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti paṣẹ pe ile-ẹjọ ni gbogbo wọn yoo kangun si lẹyin ti iwadii ba pari lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Leave a Reply