Ọpẹlọpẹ awọn araalu ti wọn fura, ti wọn si tete ta awọn agbofinro lolobo loru ọjọ Aje, Mọnde, ọse yii, awọn ni wọn jẹ kọwọ ba awọn afurasi ọdaran mẹwaa kan ti wọn fẹsun kan pe wọn lọọ bẹ agba epo labẹlẹ lati ji epo wa, ọwọ si tẹ ọkọ mẹsan-an ti wọn fi n gbọn epo sa lọ.
Agbegbe kan ti wọn n pe ni Arepo, nipinlẹ Ogun, niṣẹlẹ naa ti waye loru ọjọ Aje, Mọnde, si fẹẹrẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii; gẹgẹ bii Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), ṣe wi.
Rear Admiral Daji Ọladele tileeṣẹ ologun oju omi, to tun jẹ ọga fun Ikọ Ọpureṣan AWATSE sọrọ lori iṣẹlẹ naa, o ni inu oun dun fun bawọn olugbe agbegbe ti wọn gbe paipu epo kọja labẹlẹ ṣe wa lojufo, ti wọn si tete kan sileeṣẹ awọn.
Loju ẹsẹ lo lawọn ti lọọ ka awọn janduku naa mọ, nigba tawọn debẹ, awọn ba mọto tirela mẹfa ti wọn kọ akọle DANGOTE sara meji ninu wọn, pẹlu awọn ọkọ mẹta mi-in. Wọn n loodu epo bẹntiroolu sinu wọn lọwọ.
O ni bawọn janduku naa ṣe ri awọn ṣọja ni wọn ya danu, ṣugbọn ọwọ papa tẹ mẹwaa ninu wọn, wọn ti ko wọn lọ si bareke ologun ni Marina.
O tun sọ pe awọn olowo kan lo fori pamọ sibi kan ti wọn n ran awọn janduku wọnyi niṣẹ, ṣugbọn awọn maa ri i daju pe gbogbo wọn fimu kata ofin.
Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ NNPC ti wa lagbegbe naa lati ṣatunṣe si paipu ti wọn bẹ ọhun, paapaa lati dena ewu ijamba ina to ṣee ṣe ko ṣẹlẹ.
Mejọ Jẹnẹra Godwin Umelo naa ṣọrọ, o ni gbogbo mọto tawọn gba lọwọ awọn afurasi arufin wọnyi ni lawọn maa gbẹsẹ le, bẹẹ lo si rọ awọn eeyan lati maa ta awọn lolobo, ki awọn le ṣegun awọn ọbayejẹ ẹda to n ṣakoba fọrọ aje wa.