Ọwọ tẹ Monday, ọmọ ogun ọdun to fipa ṣe ‘kinni’ fun’ya arugbo n’Ifọn

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọwọ ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ Monday Asaba lori ẹsun fifi ipa ba iya arugbo kan lo pọ niluu Ifọn, nijọba ibilẹ Ọsẹ.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ni wọn lọkunrin ọmọ ogun ọdun ọhun lọọ ka iya ẹni ọgọta ọdun naa mọle nibi to ti fipa ṣe kinni fun un karakara, lẹyin to tẹ ifẹ inu ara rẹ lọrun tan lo sa lọ.

Ni kete tawọn ẹbi iya agbalagba ọhun gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni wọn ti lọ si tesan to wa niluu Ifọn lati lọọ fẹjọ Monday sun awọn ọlọpaa.

Ọwọ awọn agbofinro pada tẹ afurasi ọdaran naa lẹyin ọjọ diẹ ti wọn ti n wa a, loju-ẹsẹ ni wọn si ti fi i sọwọ si olu ileesẹ wọn to wa l’Akurẹ fun ẹkunrẹrẹ iwadii.

Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bọlaji Salami, ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ẹsun ti wọn fi kan Monday, o ni o digba ti awọn ba pari ifọrọwanilẹnuwo ti awọn n ṣe fun un ko too foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply