Ọwọ tẹ Onyekachi, ileeṣẹ nla kan lo lọọ ja lole l’Owode-Ẹgba

Gbenga Amos, Ogun

Ọwọ ti tẹ afurasi adigunjale ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan lagbegbe Owode Ẹgba, nipinlẹ Ogun, Onyekachi Mbamlu lorukọ ẹ. Ẹrọ abanaṣiṣẹ nla meji ti wọn fi n pọmpu omi lo lọọ ji nileeṣẹ Dany Rossy, to wa lagbegbe ohun tọwọ palaba rẹ fi segi.

Akolo awọn ẹṣọ alaabo So-Safe ti wọn n patiroolu abule Ayetoro si Owode, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, lafurasi yii ko si l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022, ni nnkan bii aago mẹta ọganjọ oru.

Ọga agba So-Safe, Kọmadaati Sọji Ganzallo, sọ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Ẹti, Furaidee, pe, Onyekachi ti fo fẹnsi wọle sinu ọgba ileeṣẹ naa pẹlu awọn irinṣẹ to ko dani, o si ti tu awọn ẹrọ nla meji ọhun, bo ṣe n lakaka lati ko wọn jade lawọn ẹṣọ naa fura pe nnkan kan n ṣẹlẹ nibẹ, ibẹ naa si ni wọn ka a mọ. Wọn lo jẹwọ pe oun atawọn kan lawọn jọ gbimọ-pọ lati jale ọhun, o lawọn yooku ti sa lọ ni.

Ganzallo lawọn ti fa afurasi ọdaran yii le awọn agbofinro lọwọ ni teṣan ọlọpaa to wa ni Mowe, pẹlu awọn ẹsibiiti ti wọn ka mọ ọn lọwọ, iṣẹ si n lọ lati wa awọn yooku to sa lọ lawaari, ki gbogbo wọn le fimu kata ofin nile-ẹjọ.

Leave a Reply