Ọwọ tẹ Sọdiq atawọn ẹgbẹ rẹ to pa Aishat sinu oko niluu Esiẹ

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Afurasi mẹrin; Adams Sodiq, ọmọ ọdun mọkandinlogun; Rasaq Rasheed, ọmọ ọdun mẹrindinlogun; Lukman Quadri, ẹni ọdun mẹẹẹdogun ati Billiamine Qayum, ọmọ ọdun mẹrindinlogun, lọwọ ajọ aabo ẹni laabo ilu, NSCDC, nipinlẹ Kwara, tẹ fẹsun pe wọn pa obinrin kan, Aishat Sanni, sinu oko niluu Esiẹ, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, nipinlẹ Kwara.

Atẹjade lati ọwọ Alukoro NSCDC ni Kwara, Babawale Zaid Afọlabi, ni ọjọ keji, oṣu kẹrin, ọdun 2021, ni Alhaji Musa Waziri to jẹ akọwe awọn ẹya Fulani ati Bororo niluu Esiẹ fi iṣẹlẹ naa to ajọ naa leti.

Lasiko iwadii nipa bi Aishat ṣe dawati ni wọn ri oku rẹ ninu oko ti wọn pa a si lọjọ kẹta, oṣu kẹrin, ọdun yii, gbogbo ara rẹ ni wọn ṣa yannayanna to si tun wa nihooho.

O ṣalaye siwaju pe, lasiko tawọn fọrọ wa wọn lẹnu wo, ohun ti wọn sọ ni pe ọkan lara awọn obinrin Bororo naa ji eeṣo kaṣu ninu oko, Sodiq Adams si gbiyanju lati mu un, ṣugbọn o pada sa lọ.

Eyi ni wọn lo mu ki Sọdiq atawọn afurasi mẹta yooku lepa Bororo keji (Aishat) titi ti wọn fi mu u balẹ.

Atẹjade naa ni nigba ti Sọdiq n gbiyanju lati fipa ba obinrin naa laṣepọ niyẹn di eyin mọ apa ati ọrun rẹ, to si ge e jẹ yannayanna.

O ni lasiko tọwọ tẹ Sọdiq, ẹjẹ wa ni gbogbo ara aṣọ to wọ lọjọ iṣẹlẹ naa.

O ni awọn ti gbe ẹjọ naa le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ lati gbe igbesẹ to ba tun yẹ lori ẹ.

Leave a Reply