Ọwọ tẹ tiṣa ti wọn lo n fipa ba ọmọ to bi ninu ara ẹ lo pọ l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Olukọ ileewe girama kan, Nelson Akinṣọwọn, lọwọ ti tẹ lori ẹsun fifipa ba ọmọ bibi inu rẹ lo pọ niluu Ondo, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo.

Ohun ta a gbọ ni pe lati igba ti ọmọbinrin naa ti wa lẹni ọdun mẹwaa lo ti n foju wina ibalopọ baba rẹ, kinni ọhun ko si figba kankan dawọ duro titi to fi di bii ọmọ ọdun mẹtadinlogun ti aṣiri ọrọ yii pada tu sita.

Ninu alaye ti ọmọbinrin ta a forukọ bo laṣiiri ọhun ṣe fawọn oniroyin kan to fọrọ wa wọn lẹnu wo, o ni ni nnkan bii ọdun meje sẹyin ni ija nla kan waye laarin awọn obi oun, leyii to ṣokunfa bawọn mejeeji ṣe kọ ara wọn silẹ gẹgẹ bii ọkọ ati aya.

O ni ko pẹ rara ti iya oun kẹru jade tan ni baba oun ti bẹrẹ si i ba oun lo pọ pẹlu ipa, eyi lo ni o saaba maa n waye nigbakuugba ti ọkunrin to n ṣiṣẹ tiṣa naa ba ti mu ọti yo.

O ni bo tilẹ jẹ pe ọpọ igba ni iyawo baba oun ti awọn jọ n gbe maa n gba oun nimọran lati yago fun iṣekuṣe, sibẹ ẹru biba ki i jẹ ki oun le sọ ohunkohun jade lori iṣẹlẹ.

Nigba tọrọ yii su oun loun sa kuro nile, ti oun si lọọ farapamọ sibi kan titi digba tawọn ọlọpaa tesan Fagun, niluu Ondo, fi ranṣẹ si i pe ko yọju sawọn.

Ṣe ni Nelson ṣẹ kanlẹ lori ẹsun ti ọmọ rẹ fi kan an to ni irọ patapata ni, o ni o da oun loju pe iyawo oun to jẹ iya ọmọ naa lo n ti i ni itikuti lati waa parọ mọ oun ni tesan.

Alukoro ileesẹ ipinlẹ Ondo, Funmi Ọdunlami, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni iwadii ṣi n tẹsiwaju, bo tilẹ jẹ pe afurasi ẹni ọdun marundinlaaadọta ọhun si n ṣẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an.

 

Leave a Reply