Ọwọ tẹ wọn o: awọn to n fi ọkada ja foonu gba nIlọrin

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Ọwọ palaba awọn ọdaran meji, Adam Taofeek ati Alabẹrẹ Adam, ti wọn maa n fi ọkada ja foonu gba lọwọ awọn araalu ti segi lagbegbe Danialu, niluu Ilọrin.

Ileeṣẹ ọlọpaa, F’ Division, lo mu awọn mejeeji lasiko ti wọn ja foonu gba lọwọ ẹni kan ti wọn si gbiyanju lati sa lọ. Alukoro ọlọpaa, Ajayi Ọkasanmi, to fidi ẹ mulẹ ṣalaye pe ko si ọlọkada kankan to ku nibi iṣẹlẹ naa. O ni kawọn araalu ma gbọ ahesọ tawọn kan n gbe kiri pe Hausa ọlọkada kan padanu ẹmi rẹ. Awọn ọlokada le awọn ọdaran naa ti wọn ti mu iṣẹ jija foonu gba ni ibaada lati Danialu titi de Tankẹ ni.

Akọroyin wa gbọ pe nigba tawọn ọdaran yii ri i pe ero ya bo wọn, ati nitori ẹru pe o ṣee ṣe ki wọn lu awọn pa, kiakia ni wọn sare jọwọ ara wọn fawọn ọlọpaa to wa ni Tankẹ. Awọn ọlọpaa yii lo ko wọn lọ sẹka to n gbogun ti iṣẹlẹ idigunjale ti wọn n pe ni SARS.

Leave a Reply