Ọwọ ti ba diẹ ninu awọn ole to n daamu awọn ara Ogijo

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Awọn gende mẹwaa yii ti wọn pe orukọ wọn ni Moses Johnson, Chinedu Okechukwu, Oka James, Mathew John, Moses David, Fuhad Sulaimon, Joseph Emmanuel, Stephen Samuel, Ozon Austin ati Ọpẹ Taiwo lọwọ ọlọpaa Ogijo ti tẹ bayii. Wọn ni awọn ni wọn n lo nnkan ija, ti wọn si n ṣe bẹẹ fipa gba dukia awọn ẹni ẹlẹni.

Ọjọ karun-un, oṣu keji, ọdun yii, lọwọ ba wọn gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi ṣe wi.

O ni Ọlaọjọ Emmanuel lo mu ẹjọ lọ si teṣan Ogijo, pe awọn ọkunrin kan da oun atiyawo oun lọna lọjọ kẹrin, oṣu yii, ni nnkan bii aago mẹsan-aabọ alẹ. Ibọn lo ni wọn yọ sawọn, ti wọn fi gba foonu nla Iphone 7 toun n lo lọ́wọ́ oun.

Emmanuel sọ fawọn ọlọpaa pe oun pada ri ninu awọn to da oun lọna yii lagbegbe Ita Oluwo, l’Ogijo, kan naa.

Lẹyin ifisun yii lọwọ ba awọn mẹwaa yii, Emmanuel atawọn mi-in ti wọn ti ja lole si ti waa tọka wọn ni teṣan naa gẹ́gẹ́ bíi ẹni to ja awọn lole.

Wọn ti taari wọn sẹka itọpinpin to lọọrin, gẹgẹ bi aṣẹ Kọmiṣanna Edward Ajogun.

Leave a Reply