Ọwọ ti ba ọrẹ meji ti wọn ṣa ọlọpaa pa nitori maaluu n’Imẹkọ-Afọn

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Kusogba Isreal; ẹni ọdun mejilelọgbọn pẹlu Oye Ṣẹgun; ẹni ogoji ọdun. Awọn mejeeji lọwọ ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ogun ti tẹ bayii lori iku Inspẹkitọ Adebayọ Adele, ọlọpaa Ibadan ti wọn ni wọn ṣa pa n’Imẹkọ- Afọn logunjọ, oṣu kẹsan-an, ọdun to kọja.

Ọjọ keji, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, lọwọ awọn Amọtẹkun tẹ wọn.

Gẹgẹ bi CP David Akinrẹmi, ọga Amọtẹkun ipinlẹ Ogun ṣe wi, o ni ọkunrin alapata kan torukọ ẹ n jẹ Aminu Azeez, ni wọn lo ra maaluu tawọn kan ji n’Ibadan, bẹẹ, ẹnikan lo ni awọn maaluu yii, ti Aminu ra a, to si ko o wa s’Imẹkọ.

Ẹni to ni awọn maaluu naa lo lọọ   sọ f’ọlọpaa, n’Ibadan, ti wọn fi wa lati mu Aminu lọ loṣu kẹsan-an naa.

Ṣugbọn nigba tawọn ọlọpaa naa de, Aminu ko jẹ ki wọn mu oun, bẹẹ lo paṣẹ fun awọn yooku rẹ ti wọn to mẹrinla, tawọn naa jẹ alapata lati doju ija kọ awọn ọlọpaa ọhun, nibẹ ni wọn si ti ṣa Inspẹkitọ Adebayọ Adele ladaa, eyi to pada yọri siku fun un.

Awọn meji tọwọ ṣẹṣẹ bayii ni wọn ni wọn mọ nipa bi wọn ṣe ṣa ọlọpaa naa pa,  Amọtẹkun si ti fa wọn le ọlọpaa Ibadan lọwọ, bẹẹ ni iṣẹ n lọ lati mu awọn yooku ti wọn tun lọwọ si iṣẹlẹ yii.

Leave a Reply